Quran Apps in many lanuages:

Surah Fatir Ayahs #6 Translated in Yoruba

مَا يَفْتَحِ اللَّهُ لِلنَّاسِ مِنْ رَحْمَةٍ فَلَا مُمْسِكَ لَهَا ۖ وَمَا يُمْسِكْ فَلَا مُرْسِلَ لَهُ مِنْ بَعْدِهِ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Ohunkohun ti Allahu ba si ona re sile ninu ike fun awon eniyan, ko si eni ti o le da a duro. Ohunkohun ti O ba si mu dani, ko si eni ti o le mu un wa leyin Re. Oun si ni Alagbara, Ologbon
يَا أَيُّهَا النَّاسُ اذْكُرُوا نِعْمَتَ اللَّهِ عَلَيْكُمْ ۚ هَلْ مِنْ خَالِقٍ غَيْرُ اللَّهِ يَرْزُقُكُمْ مِنَ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ ۚ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ فَأَنَّىٰ تُؤْفَكُونَ
Eyin eniyan, e ranti idera Allahu lori yin. Nje eledaa kan yato si Allahu tun wa ti o n pese fun yin lati inu sanmo ati ile? Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, bawo ni won se n se yin lori kuro nibi ododo
وَإِنْ يُكَذِّبُوكَ فَقَدْ كُذِّبَتْ رُسُلٌ مِنْ قَبْلِكَ ۚ وَإِلَى اللَّهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ
Ti won ba pe o ni opuro, won kuku ti pe awon Ojise kan ni opuro siwaju re. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si
يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّ وَعْدَ اللَّهِ حَقٌّ ۖ فَلَا تَغُرَّنَّكُمُ الْحَيَاةُ الدُّنْيَا ۖ وَلَا يَغُرَّنَّكُمْ بِاللَّهِ الْغَرُورُ
Eyin eniyan, dajudaju adehun Allahu ni ododo. E ma se je ki isemi aye tan yin je. Ki e si ma se je ki (Esu) eletan tan yin je
إِنَّ الشَّيْطَانَ لَكُمْ عَدُوٌّ فَاتَّخِذُوهُ عَدُوًّا ۚ إِنَّمَا يَدْعُو حِزْبَهُ لِيَكُونُوا مِنْ أَصْحَابِ السَّعِيرِ
Dajudaju Esu ni ota fun yin. Nitori naa, e mu un ni ota. O kan n pe awon ijo re nitori ki won le je ero inu Ina t’o n jo fofo

Choose other languages: