Quran Apps in many lanuages:

Surah Fatir Ayahs #9 Translated in Yoruba

يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّ وَعْدَ اللَّهِ حَقٌّ ۖ فَلَا تَغُرَّنَّكُمُ الْحَيَاةُ الدُّنْيَا ۖ وَلَا يَغُرَّنَّكُمْ بِاللَّهِ الْغَرُورُ
Eyin eniyan, dajudaju adehun Allahu ni ododo. E ma se je ki isemi aye tan yin je. Ki e si ma se je ki (Esu) eletan tan yin je
إِنَّ الشَّيْطَانَ لَكُمْ عَدُوٌّ فَاتَّخِذُوهُ عَدُوًّا ۚ إِنَّمَا يَدْعُو حِزْبَهُ لِيَكُونُوا مِنْ أَصْحَابِ السَّعِيرِ
Dajudaju Esu ni ota fun yin. Nitori naa, e mu un ni ota. O kan n pe awon ijo re nitori ki won le je ero inu Ina t’o n jo fofo
الَّذِينَ كَفَرُوا لَهُمْ عَذَابٌ شَدِيدٌ ۖ وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَهُمْ مَغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ كَبِيرٌ
Awon t’o sai gbagbo, iya lile n be fun won. Awon t’o si gbagbo ni ododo, ti won se ise rere, aforijin ati esan t’o tobi n be fun won
أَفَمَنْ زُيِّنَ لَهُ سُوءُ عَمَلِهِ فَرَآهُ حَسَنًا ۖ فَإِنَّ اللَّهَ يُضِلُّ مَنْ يَشَاءُ وَيَهْدِي مَنْ يَشَاءُ ۖ فَلَا تَذْهَبْ نَفْسُكَ عَلَيْهِمْ حَسَرَاتٍ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ بِمَا يَصْنَعُونَ
Se eni ti won se ise aburu owo re ni oso fun, ti o si n ri i ni (ise) daadaa, (l’o fe banuje le lori?) Dajudaju Allahu n si eni ti O ba fe lona. O si n fi ona mo eni ti O ba fe. Nitori naa, ma se banuje nitori tiwon. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti won n se
وَاللَّهُ الَّذِي أَرْسَلَ الرِّيَاحَ فَتُثِيرُ سَحَابًا فَسُقْنَاهُ إِلَىٰ بَلَدٍ مَيِّتٍ فَأَحْيَيْنَا بِهِ الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ كَذَٰلِكَ النُّشُورُ
Allahu ni Eni ti O fi awon ategun ranse. (Ategun naa) si maa tu esujo soke. A si fi fun ilu (ti ile re) ti ku lomi mu. A si fi ta ile naa ji leyin ti o ti ku. Bayen ni ajinde (eda yo se ri)

Choose other languages: