Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #74 Translated in Yoruba

أَلَمْ يَأْتِهِمْ نَبَأُ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ قَوْمِ نُوحٍ وَعَادٍ وَثَمُودَ وَقَوْمِ إِبْرَاهِيمَ وَأَصْحَابِ مَدْيَنَ وَالْمُؤْتَفِكَاتِ ۚ أَتَتْهُمْ رُسُلُهُمْ بِالْبَيِّنَاتِ ۖ فَمَا كَانَ اللَّهُ لِيَظْلِمَهُمْ وَلَٰكِنْ كَانُوا أَنْفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
Se iroyin awon t’o siwaju won ko ti i de ba won ni? (Iroyin) ijo (Anabi) Nuh, iran ‘Ad, iran Thamud, ijo (Anabi) ’Ibrohim, awon ara Modyan ati awon ilu ti A doju re bole (ijo Anabi Lut); awon Ojise won wa ba won pelu awon eri t’o yanju. Nitori naa, Allahu ko se abosi si won, sugbon emi ara won ni won sabosi si
وَالْمُؤْمِنُونَ وَالْمُؤْمِنَاتُ بَعْضُهُمْ أَوْلِيَاءُ بَعْضٍ ۚ يَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنْكَرِ وَيُقِيمُونَ الصَّلَاةَ وَيُؤْتُونَ الزَّكَاةَ وَيُطِيعُونَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ ۚ أُولَٰئِكَ سَيَرْحَمُهُمُ اللَّهُ ۗ إِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin, apa kan won lore apa kan; won n pase ohun rere, won n ko ohun buruku, won n kirun, won n yo Zakah, won si n tele ti Allahu ati Ojise Re. Awon wonyen ni Allahu yoo sake. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon
وَعَدَ اللَّهُ الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا وَمَسَاكِنَ طَيِّبَةً فِي جَنَّاتِ عَدْنٍ ۚ وَرِضْوَانٌ مِنَ اللَّهِ أَكْبَرُ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ
Allahu se adehun awon Ogba Idera fun awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin, eyi ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. (O tun se adehun) awon ibugbe t’o dara ninu awon ogba idera ‘Adni (fun won). Iyonu lati odo Allahu l’o si tobi julo (fun won). Iyen, ohun ni erenje nla
يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ جَاهِدِ الْكُفَّارَ وَالْمُنَافِقِينَ وَاغْلُظْ عَلَيْهِمْ ۚ وَمَأْوَاهُمْ جَهَنَّمُ ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ
Iwo Anabi, gbogun ti awon alaigbagbo ati awon sobe-selu musulumi. Ki o si le mo won. Ina Jahanamo ni ibugbe won. Ikangun naa si buru
يَحْلِفُونَ بِاللَّهِ مَا قَالُوا وَلَقَدْ قَالُوا كَلِمَةَ الْكُفْرِ وَكَفَرُوا بَعْدَ إِسْلَامِهِمْ وَهَمُّوا بِمَا لَمْ يَنَالُوا ۚ وَمَا نَقَمُوا إِلَّا أَنْ أَغْنَاهُمُ اللَّهُ وَرَسُولُهُ مِنْ فَضْلِهِ ۚ فَإِنْ يَتُوبُوا يَكُ خَيْرًا لَهُمْ ۖ وَإِنْ يَتَوَلَّوْا يُعَذِّبْهُمُ اللَّهُ عَذَابًا أَلِيمًا فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ ۚ وَمَا لَهُمْ فِي الْأَرْضِ مِنْ وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ
Won n fi Allahu bura pe awon ko soro (buruku). Won si kuku ti so oro aigbagbo, won si sai gbagbo leyin ti won ti gba ’Islam. Won tun gberokero si nnkan ti owo won ko nii ba. Won ko tako kini kan bi ko se nitori pe Allahu ati Ojise Re ro awon (Sohabah) loro ninu ola Re. Ti won ba ronu piwada, o maa dara fun won. Ti won ba si koyin (si yin), Allahu yoo je won niya eleta-elero ni aye ati ni orun. Ko si nii si alaabo ati alaranse kan fun won lori ile aye

Choose other languages: