Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #76 Translated in Yoruba

وَعَدَ اللَّهُ الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا وَمَسَاكِنَ طَيِّبَةً فِي جَنَّاتِ عَدْنٍ ۚ وَرِضْوَانٌ مِنَ اللَّهِ أَكْبَرُ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ
Allahu se adehun awon Ogba Idera fun awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin, eyi ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. (O tun se adehun) awon ibugbe t’o dara ninu awon ogba idera ‘Adni (fun won). Iyonu lati odo Allahu l’o si tobi julo (fun won). Iyen, ohun ni erenje nla
يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ جَاهِدِ الْكُفَّارَ وَالْمُنَافِقِينَ وَاغْلُظْ عَلَيْهِمْ ۚ وَمَأْوَاهُمْ جَهَنَّمُ ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ
Iwo Anabi, gbogun ti awon alaigbagbo ati awon sobe-selu musulumi. Ki o si le mo won. Ina Jahanamo ni ibugbe won. Ikangun naa si buru
يَحْلِفُونَ بِاللَّهِ مَا قَالُوا وَلَقَدْ قَالُوا كَلِمَةَ الْكُفْرِ وَكَفَرُوا بَعْدَ إِسْلَامِهِمْ وَهَمُّوا بِمَا لَمْ يَنَالُوا ۚ وَمَا نَقَمُوا إِلَّا أَنْ أَغْنَاهُمُ اللَّهُ وَرَسُولُهُ مِنْ فَضْلِهِ ۚ فَإِنْ يَتُوبُوا يَكُ خَيْرًا لَهُمْ ۖ وَإِنْ يَتَوَلَّوْا يُعَذِّبْهُمُ اللَّهُ عَذَابًا أَلِيمًا فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ ۚ وَمَا لَهُمْ فِي الْأَرْضِ مِنْ وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ
Won n fi Allahu bura pe awon ko soro (buruku). Won si kuku ti so oro aigbagbo, won si sai gbagbo leyin ti won ti gba ’Islam. Won tun gberokero si nnkan ti owo won ko nii ba. Won ko tako kini kan bi ko se nitori pe Allahu ati Ojise Re ro awon (Sohabah) loro ninu ola Re. Ti won ba ronu piwada, o maa dara fun won. Ti won ba si koyin (si yin), Allahu yoo je won niya eleta-elero ni aye ati ni orun. Ko si nii si alaabo ati alaranse kan fun won lori ile aye
وَمِنْهُمْ مَنْ عَاهَدَ اللَّهَ لَئِنْ آتَانَا مِنْ فَضْلِهِ لَنَصَّدَّقَنَّ وَلَنَكُونَنَّ مِنَ الصَّالِحِينَ
O wa ninu won, eni t’o ba Allahu se adehun pe: "Ti O ba fun wa ninu oore-ajulo Re, dajudaju a oo maa tore, dajudaju a o si wa ninu awon eni ire
فَلَمَّا آتَاهُمْ مِنْ فَضْلِهِ بَخِلُوا بِهِ وَتَوَلَّوْا وَهُمْ مُعْرِضُونَ
Amo nigba ti O fun won ninu oore-ajulo Re, won sahun si I. Won peyin da, won si n gbunri (lati nawo fesin)

Choose other languages: