Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #78 Translated in Yoruba

يَحْلِفُونَ بِاللَّهِ مَا قَالُوا وَلَقَدْ قَالُوا كَلِمَةَ الْكُفْرِ وَكَفَرُوا بَعْدَ إِسْلَامِهِمْ وَهَمُّوا بِمَا لَمْ يَنَالُوا ۚ وَمَا نَقَمُوا إِلَّا أَنْ أَغْنَاهُمُ اللَّهُ وَرَسُولُهُ مِنْ فَضْلِهِ ۚ فَإِنْ يَتُوبُوا يَكُ خَيْرًا لَهُمْ ۖ وَإِنْ يَتَوَلَّوْا يُعَذِّبْهُمُ اللَّهُ عَذَابًا أَلِيمًا فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ ۚ وَمَا لَهُمْ فِي الْأَرْضِ مِنْ وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ
Won n fi Allahu bura pe awon ko soro (buruku). Won si kuku ti so oro aigbagbo, won si sai gbagbo leyin ti won ti gba ’Islam. Won tun gberokero si nnkan ti owo won ko nii ba. Won ko tako kini kan bi ko se nitori pe Allahu ati Ojise Re ro awon (Sohabah) loro ninu ola Re. Ti won ba ronu piwada, o maa dara fun won. Ti won ba si koyin (si yin), Allahu yoo je won niya eleta-elero ni aye ati ni orun. Ko si nii si alaabo ati alaranse kan fun won lori ile aye
وَمِنْهُمْ مَنْ عَاهَدَ اللَّهَ لَئِنْ آتَانَا مِنْ فَضْلِهِ لَنَصَّدَّقَنَّ وَلَنَكُونَنَّ مِنَ الصَّالِحِينَ
O wa ninu won, eni t’o ba Allahu se adehun pe: "Ti O ba fun wa ninu oore-ajulo Re, dajudaju a oo maa tore, dajudaju a o si wa ninu awon eni ire
فَلَمَّا آتَاهُمْ مِنْ فَضْلِهِ بَخِلُوا بِهِ وَتَوَلَّوْا وَهُمْ مُعْرِضُونَ
Amo nigba ti O fun won ninu oore-ajulo Re, won sahun si I. Won peyin da, won si n gbunri (lati nawo fesin)
فَأَعْقَبَهُمْ نِفَاقًا فِي قُلُوبِهِمْ إِلَىٰ يَوْمِ يَلْقَوْنَهُ بِمَا أَخْلَفُوا اللَّهَ مَا وَعَدُوهُ وَبِمَا كَانُوا يَكْذِبُونَ
Nitori naa, ahun won mu oro won kangun si isobe-selu ninu okan won titi di ojo ti won yoo pade Allahu nitori pe won ye adehun ti won ba Allahu se ati nitori pe won n paro
أَلَمْ يَعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ سِرَّهُمْ وَنَجْوَاهُمْ وَأَنَّ اللَّهَ عَلَّامُ الْغُيُوبِ
Se won ko mo pe Allahu mo asiri won ati oro ateso won, ati pe dajudaju Allahu ni Onimo nipa awon ikoko

Choose other languages: