Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #69 Translated in Yoruba

وَلَئِنْ سَأَلْتَهُمْ لَيَقُولُنَّ إِنَّمَا كُنَّا نَخُوضُ وَنَلْعَبُ ۚ قُلْ أَبِاللَّهِ وَآيَاتِهِ وَرَسُولِهِ كُنْتُمْ تَسْتَهْزِئُونَ
Ti o ba kuku bi won leere, dajudaju won a wi pe: "Awa kan n rojo lasan ni, a si n sawada ni." So pe: "Se Allahu, awon ayah Re ati Ojise Re ni e n fi se yeye
لَا تَعْتَذِرُوا قَدْ كَفَرْتُمْ بَعْدَ إِيمَانِكُمْ ۚ إِنْ نَعْفُ عَنْ طَائِفَةٍ مِنْكُمْ نُعَذِّبْ طَائِفَةً بِأَنَّهُمْ كَانُوا مُجْرِمِينَ
E ma se mu awawi wa. Dajudaju e ti sai gbagbo leyin igbagbo yin. Ti A ba se amojukuro fun apa kan ninu yin, A oo fiya je apa kan nitori pe won je elese
الْمُنَافِقُونَ وَالْمُنَافِقَاتُ بَعْضُهُمْ مِنْ بَعْضٍ ۚ يَأْمُرُونَ بِالْمُنْكَرِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ الْمَعْرُوفِ وَيَقْبِضُونَ أَيْدِيَهُمْ ۚ نَسُوا اللَّهَ فَنَسِيَهُمْ ۗ إِنَّ الْمُنَافِقِينَ هُمُ الْفَاسِقُونَ
Awon sobe-selu musulumi lokunrin ati awon sobe-selu musulumo lobinrin, iru kan-un ni won; won n pase ohun buruku, won n ko ohun rere, won si n kawo gbera (lati nawo fesin). Won gbagbe Allahu. Nitori naa, Allahu gbagbe won. Dajudaju awon sobe-selu musulumi, awon ni obileje
وَعَدَ اللَّهُ الْمُنَافِقِينَ وَالْمُنَافِقَاتِ وَالْكُفَّارَ نَارَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ هِيَ حَسْبُهُمْ ۚ وَلَعَنَهُمُ اللَّهُ ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ مُقِيمٌ
Allahu si ti se adehun ina Jahanamo fun awon sobe-selu musulumi lokunrin ati awon sobe-selu musulumo lobinrin ati awon alaigbagbo. Olusegbere ni won ninu re. Ina maa to won. Allahu si ti sebi le won. Iya gbere si wa fun won
كَالَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ كَانُوا أَشَدَّ مِنْكُمْ قُوَّةً وَأَكْثَرَ أَمْوَالًا وَأَوْلَادًا فَاسْتَمْتَعُوا بِخَلَاقِهِمْ فَاسْتَمْتَعْتُمْ بِخَلَاقِكُمْ كَمَا اسْتَمْتَعَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ بِخَلَاقِهِمْ وَخُضْتُمْ كَالَّذِي خَاضُوا ۚ أُولَٰئِكَ حَبِطَتْ أَعْمَالُهُمْ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ
(Awon sobe-selu musulumi da) gege bi awon t’o siwaju yin; won le ju yin lo ni agbara, won si po (ju yin lo) ni awon dukia ati awon omo. Nigba naa, won je igbadun ipin tiwon (ninu oore aye). Eyin (sobe-selu wonyii naa yoo) je igbadun ipin tiyin gege bi awon t’o siwaju yin se je igbadun ipin tiwon. Eyin naa si sosokuso bi eyi ti awon naa so ni isokuso. Awon wonyen, awon ise won ti baje ni aye ati ni orun. Awon wonyen, awon si ni eni ofo

Choose other languages: