Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #68 Translated in Yoruba

يَحْذَرُ الْمُنَافِقُونَ أَنْ تُنَزَّلَ عَلَيْهِمْ سُورَةٌ تُنَبِّئُهُمْ بِمَا فِي قُلُوبِهِمْ ۚ قُلِ اسْتَهْزِئُوا إِنَّ اللَّهَ مُخْرِجٌ مَا تَحْذَرُونَ
Awon sobe-selu musulumi n beru pe ki A ma se so surah kan kale nipa won, ti o maa fun won ni iro ohun ti n be ninu okan won. So pe: "E maa se yeye lo. Dajudaju Allahu yoo safi han ohun ti e n beru
وَلَئِنْ سَأَلْتَهُمْ لَيَقُولُنَّ إِنَّمَا كُنَّا نَخُوضُ وَنَلْعَبُ ۚ قُلْ أَبِاللَّهِ وَآيَاتِهِ وَرَسُولِهِ كُنْتُمْ تَسْتَهْزِئُونَ
Ti o ba kuku bi won leere, dajudaju won a wi pe: "Awa kan n rojo lasan ni, a si n sawada ni." So pe: "Se Allahu, awon ayah Re ati Ojise Re ni e n fi se yeye
لَا تَعْتَذِرُوا قَدْ كَفَرْتُمْ بَعْدَ إِيمَانِكُمْ ۚ إِنْ نَعْفُ عَنْ طَائِفَةٍ مِنْكُمْ نُعَذِّبْ طَائِفَةً بِأَنَّهُمْ كَانُوا مُجْرِمِينَ
E ma se mu awawi wa. Dajudaju e ti sai gbagbo leyin igbagbo yin. Ti A ba se amojukuro fun apa kan ninu yin, A oo fiya je apa kan nitori pe won je elese
الْمُنَافِقُونَ وَالْمُنَافِقَاتُ بَعْضُهُمْ مِنْ بَعْضٍ ۚ يَأْمُرُونَ بِالْمُنْكَرِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ الْمَعْرُوفِ وَيَقْبِضُونَ أَيْدِيَهُمْ ۚ نَسُوا اللَّهَ فَنَسِيَهُمْ ۗ إِنَّ الْمُنَافِقِينَ هُمُ الْفَاسِقُونَ
Awon sobe-selu musulumi lokunrin ati awon sobe-selu musulumo lobinrin, iru kan-un ni won; won n pase ohun buruku, won n ko ohun rere, won si n kawo gbera (lati nawo fesin). Won gbagbe Allahu. Nitori naa, Allahu gbagbe won. Dajudaju awon sobe-selu musulumi, awon ni obileje
وَعَدَ اللَّهُ الْمُنَافِقِينَ وَالْمُنَافِقَاتِ وَالْكُفَّارَ نَارَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ هِيَ حَسْبُهُمْ ۚ وَلَعَنَهُمُ اللَّهُ ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ مُقِيمٌ
Allahu si ti se adehun ina Jahanamo fun awon sobe-selu musulumi lokunrin ati awon sobe-selu musulumo lobinrin ati awon alaigbagbo. Olusegbere ni won ninu re. Ina maa to won. Allahu si ti sebi le won. Iya gbere si wa fun won

Choose other languages: