Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #127 Translated in Yoruba

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا قَاتِلُوا الَّذِينَ يَلُونَكُمْ مِنَ الْكُفَّارِ وَلْيَجِدُوا فِيكُمْ غِلْظَةً ۚ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ مَعَ الْمُتَّقِينَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e gbogun ti awon t’o sunmo yin ninu awon alaigbagbo; ki won ri ilekoko lara yin. Ki e si mo pe dajudaju Allahu wa pelu awon oluberu (Re)
وَإِذَا مَا أُنْزِلَتْ سُورَةٌ فَمِنْهُمْ مَنْ يَقُولُ أَيُّكُمْ زَادَتْهُ هَٰذِهِ إِيمَانًا ۚ فَأَمَّا الَّذِينَ آمَنُوا فَزَادَتْهُمْ إِيمَانًا وَهُمْ يَسْتَبْشِرُونَ
Nigba ti A ba si so surah kan kale, o n be ninu won eni ti o maa wi pe: “Ta ni ninu yin ni eyi le igbagbo (re) kun?” Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, (ayah naa) yo si le igbagbo (won) kun. Won yo si maa dunnu
وَأَمَّا الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمْ مَرَضٌ فَزَادَتْهُمْ رِجْسًا إِلَىٰ رِجْسِهِمْ وَمَاتُوا وَهُمْ كَافِرُونَ
Ni ti awon ti aisan si wa ninu okan won, (ayah naa) yo si se alekun egbin si egbin won. Won yo si ku si ipo alaigbagbo
أَوَلَا يَرَوْنَ أَنَّهُمْ يُفْتَنُونَ فِي كُلِّ عَامٍ مَرَّةً أَوْ مَرَّتَيْنِ ثُمَّ لَا يَتُوبُونَ وَلَا هُمْ يَذَّكَّرُونَ
Se won ko ri i pe A n dan won wo ni ee kan tabi ee meji ni odoodun. Leyin naa, won ko ronu piwada, won ko si lo iranti
وَإِذَا مَا أُنْزِلَتْ سُورَةٌ نَظَرَ بَعْضُهُمْ إِلَىٰ بَعْضٍ هَلْ يَرَاكُمْ مِنْ أَحَدٍ ثُمَّ انْصَرَفُوا ۚ صَرَفَ اللَّهُ قُلُوبَهُمْ بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَا يَفْقَهُونَ
Ati pe nigba ti A ba so surah kan kale, apa kan won yoo wo apa kan loju (won yo si wi pe): “Se eni kan n wo yin bi?” Leyin naa, won maa peyinda. Allahu si pa okan won da (sodi) nitori pe dajudaju awon ni ijo kan ti ko gbo agboye

Choose other languages: