Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #116 Translated in Yoruba

التَّائِبُونَ الْعَابِدُونَ الْحَامِدُونَ السَّائِحُونَ الرَّاكِعُونَ السَّاجِدُونَ الْآمِرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَالنَّاهُونَ عَنِ الْمُنْكَرِ وَالْحَافِظُونَ لِحُدُودِ اللَّهِ ۗ وَبَشِّرِ الْمُؤْمِنِينَ
Awon oluronupiwada, awon olujosin (fun Allahu), awon oludupe (fun Allahu), awon alaaawe, awon oludawote-orunkun (lori irun), awon oluforikanle (fun Allahu), awon olupase-ohun rere, awon oluko-ohun buruku ati awon oluso-enu-ala ti Allahu gbekale, fun awon onigbagbo ododo (wonyi) ni iro idunnu (Ogba Idera)
مَا كَانَ لِلنَّبِيِّ وَالَّذِينَ آمَنُوا أَنْ يَسْتَغْفِرُوا لِلْمُشْرِكِينَ وَلَوْ كَانُوا أُولِي قُرْبَىٰ مِنْ بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمْ أَنَّهُمْ أَصْحَابُ الْجَحِيمِ
Ko ye fun Anabi ati awon t’o gbagbo lododo lati toro aforijin fun awon osebo, won ibaa je ebi, leyin ti o ti han si won pe dajudaju ero inu ina Jehim ni won
وَمَا كَانَ اسْتِغْفَارُ إِبْرَاهِيمَ لِأَبِيهِ إِلَّا عَنْ مَوْعِدَةٍ وَعَدَهَا إِيَّاهُ فَلَمَّا تَبَيَّنَ لَهُ أَنَّهُ عَدُوٌّ لِلَّهِ تَبَرَّأَ مِنْهُ ۚ إِنَّ إِبْرَاهِيمَ لَأَوَّاهٌ حَلِيمٌ
Ati pe aforijin ti (Anabi) ’Ibrohim toro fun baba re ko si je kini kan bi ko se nitori adehun t’o se fun un. Sugbon nigba ti o han si i pe dajudaju ota Allahu ni (baba re), o yowo yose kuro ninu re. Dajudaju (Anabi) ’Ibrohim ni oluraworase, olufarada
وَمَا كَانَ اللَّهُ لِيُضِلَّ قَوْمًا بَعْدَ إِذْ هَدَاهُمْ حَتَّىٰ يُبَيِّنَ لَهُمْ مَا يَتَّقُونَ ۚ إِنَّ اللَّهَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ
Allahu ki i mu isina ba ijo kan, leyin igba ti O ti to won sona, titi (Allahu) yoo fi se alaye nnkan ti won maa sora fun fun won. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan
إِنَّ اللَّهَ لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ يُحْيِي وَيُمِيتُ ۚ وَمَا لَكُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ مِنْ وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ
Dajudaju Allahu l’o ni ijoba awon sanmo ati ile. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Ko si si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu

Choose other languages: