Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #119 Translated in Yoruba

وَمَا كَانَ اللَّهُ لِيُضِلَّ قَوْمًا بَعْدَ إِذْ هَدَاهُمْ حَتَّىٰ يُبَيِّنَ لَهُمْ مَا يَتَّقُونَ ۚ إِنَّ اللَّهَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ
Allahu ki i mu isina ba ijo kan, leyin igba ti O ti to won sona, titi (Allahu) yoo fi se alaye nnkan ti won maa sora fun fun won. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan
إِنَّ اللَّهَ لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ يُحْيِي وَيُمِيتُ ۚ وَمَا لَكُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ مِنْ وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ
Dajudaju Allahu l’o ni ijoba awon sanmo ati ile. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Ko si si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu
لَقَدْ تَابَ اللَّهُ عَلَى النَّبِيِّ وَالْمُهَاجِرِينَ وَالْأَنْصَارِ الَّذِينَ اتَّبَعُوهُ فِي سَاعَةِ الْعُسْرَةِ مِنْ بَعْدِ مَا كَادَ يَزِيغُ قُلُوبُ فَرِيقٍ مِنْهُمْ ثُمَّ تَابَ عَلَيْهِمْ ۚ إِنَّهُ بِهِمْ رَءُوفٌ رَحِيمٌ
Dajudaju Allahu ti gba ironupiwada Anabi, awon Muhajirun ati awon ’Ansor, awon t’o tele e ni akoko isoro leyin ti okan igun kan ninu won fee yi pada, (amo) leyin naa, Allahu gba ironupiwada won. Dajudaju Oun ni Alaaanu, Asake-orun fun won
وَعَلَى الثَّلَاثَةِ الَّذِينَ خُلِّفُوا حَتَّىٰ إِذَا ضَاقَتْ عَلَيْهِمُ الْأَرْضُ بِمَا رَحُبَتْ وَضَاقَتْ عَلَيْهِمْ أَنْفُسُهُمْ وَظَنُّوا أَنْ لَا مَلْجَأَ مِنَ اللَّهِ إِلَّا إِلَيْهِ ثُمَّ تَابَ عَلَيْهِمْ لِيَتُوبُوا ۚ إِنَّ اللَّهَ هُوَ التَّوَّابُ الرَّحِيمُ
(O tun gba ironupiwada) awon meta ti A (so oro won ro ninu awon olusaseyin fun ogun Tabuk. Awon musulumi si deye si won) titi ile fi ha mo won tohun ti bi o se feju to. Oro ara won si su ara won. Won si mo (ni amodaju) pe ko si ibusasi kan ti awon fi le sa mo Allahu lowo afi ki won sa si odo Re. Leyin naa, Allahu gba ironupiwada won nitori ki won le maa ronu piwada. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللَّهَ وَكُونُوا مَعَ الصَّادِقِينَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu, ki e si wa pelu awon olododo

Choose other languages: