Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #120 Translated in Yoruba

إِنَّ اللَّهَ لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ يُحْيِي وَيُمِيتُ ۚ وَمَا لَكُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ مِنْ وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ
Dajudaju Allahu l’o ni ijoba awon sanmo ati ile. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Ko si si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu
لَقَدْ تَابَ اللَّهُ عَلَى النَّبِيِّ وَالْمُهَاجِرِينَ وَالْأَنْصَارِ الَّذِينَ اتَّبَعُوهُ فِي سَاعَةِ الْعُسْرَةِ مِنْ بَعْدِ مَا كَادَ يَزِيغُ قُلُوبُ فَرِيقٍ مِنْهُمْ ثُمَّ تَابَ عَلَيْهِمْ ۚ إِنَّهُ بِهِمْ رَءُوفٌ رَحِيمٌ
Dajudaju Allahu ti gba ironupiwada Anabi, awon Muhajirun ati awon ’Ansor, awon t’o tele e ni akoko isoro leyin ti okan igun kan ninu won fee yi pada, (amo) leyin naa, Allahu gba ironupiwada won. Dajudaju Oun ni Alaaanu, Asake-orun fun won
وَعَلَى الثَّلَاثَةِ الَّذِينَ خُلِّفُوا حَتَّىٰ إِذَا ضَاقَتْ عَلَيْهِمُ الْأَرْضُ بِمَا رَحُبَتْ وَضَاقَتْ عَلَيْهِمْ أَنْفُسُهُمْ وَظَنُّوا أَنْ لَا مَلْجَأَ مِنَ اللَّهِ إِلَّا إِلَيْهِ ثُمَّ تَابَ عَلَيْهِمْ لِيَتُوبُوا ۚ إِنَّ اللَّهَ هُوَ التَّوَّابُ الرَّحِيمُ
(O tun gba ironupiwada) awon meta ti A (so oro won ro ninu awon olusaseyin fun ogun Tabuk. Awon musulumi si deye si won) titi ile fi ha mo won tohun ti bi o se feju to. Oro ara won si su ara won. Won si mo (ni amodaju) pe ko si ibusasi kan ti awon fi le sa mo Allahu lowo afi ki won sa si odo Re. Leyin naa, Allahu gba ironupiwada won nitori ki won le maa ronu piwada. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللَّهَ وَكُونُوا مَعَ الصَّادِقِينَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu, ki e si wa pelu awon olododo
مَا كَانَ لِأَهْلِ الْمَدِينَةِ وَمَنْ حَوْلَهُمْ مِنَ الْأَعْرَابِ أَنْ يَتَخَلَّفُوا عَنْ رَسُولِ اللَّهِ وَلَا يَرْغَبُوا بِأَنْفُسِهِمْ عَنْ نَفْسِهِ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ لَا يُصِيبُهُمْ ظَمَأٌ وَلَا نَصَبٌ وَلَا مَخْمَصَةٌ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَلَا يَطَئُونَ مَوْطِئًا يَغِيظُ الْكُفَّارَ وَلَا يَنَالُونَ مِنْ عَدُوٍّ نَيْلًا إِلَّا كُتِبَ لَهُمْ بِهِ عَمَلٌ صَالِحٌ ۚ إِنَّ اللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجْرَ الْمُحْسِنِينَ
Ko letoo fun awon ara ilu Modinah ati eni ti o wa ni ayika won ninu awon Larubawa oko lati sa seyin fun Ojise Allahu (nipa ogun esin. Ko si letoo fun won) lati feran emi ara won ju emi re. Iyen nitori pe dajudaju ongbe, inira tabi ebi kan ko nii sele si won loju ogun loju ona (esin) Allahu, tabi won ko nii te ona kan ti n bi awon alaigbagbo ninu, tabi owo won ko nii ba kini kan lara ota afi ki A fi ko ise rere sile fun won. Dajudaju Allahu ko nii fi esan awon oluse-rere rare

Choose other languages: