Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rum Ayahs #46 Translated in Yoruba

قُلْ سِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَانْظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ مِنْ قَبْلُ ۚ كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُشْرِكِينَ
So pe: “E rin lori ile, ki e wo bi atubotan awon t’o siwaju se ri! Opolopo won ni won je osebo.”
فَأَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ الْقَيِّمِ مِنْ قَبْلِ أَنْ يَأْتِيَ يَوْمٌ لَا مَرَدَّ لَهُ مِنَ اللَّهِ ۖ يَوْمَئِذٍ يَصَّدَّعُونَ
Nitori naa, doju re ko esin t’o feserinle siwaju ki ojo kan to de, ti ko si nnkan ti o le ye e lodo Allahu. Ni ojo yen ni awon eniyan yoo pinya si (ero Ogba Idera ati ero Ina)
مَنْ كَفَرَ فَعَلَيْهِ كُفْرُهُ ۖ وَمَنْ عَمِلَ صَالِحًا فَلِأَنْفُسِهِمْ يَمْهَدُونَ
Enikeni ti o ba sai gbagbo, ori ara re ni (iya) aigbagbo re wa. Enikeni ti o ba si se ise rere, emi ara won ni won n te ite (Ogba Idera) sile fun
لِيَجْزِيَ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ مِنْ فَضْلِهِ ۚ إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الْكَافِرِينَ
nitori ki (Allahu) le san esan rere ninu oore ajulo Re fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere. Dajudaju (Allahu) ko nifee awon alaigbagbo
وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ يُرْسِلَ الرِّيَاحَ مُبَشِّرَاتٍ وَلِيُذِيقَكُمْ مِنْ رَحْمَتِهِ وَلِتَجْرِيَ الْفُلْكُ بِأَمْرِهِ وَلِتَبْتَغُوا مِنْ فَضْلِهِ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Ninu awon ami Re ni pe, O n ran ategun ni iro idunnu. Ati pe nitori ki (Allahu) le fun yin to wo ninu ike Re; ati nitori ki oko oju-omi le rin loju-omi pelu ase Re; ati nitori ki e le wa ninu oore Re; ati nitori ki e le dupe

Choose other languages: