Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rum Ayahs #45 Translated in Yoruba

ظَهَرَ الْفَسَادُ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ بِمَا كَسَبَتْ أَيْدِي النَّاسِ لِيُذِيقَهُمْ بَعْضَ الَّذِي عَمِلُوا لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ
Ibaje han lori ile ati loju omi nipase ohun ti owo awon eniyan se nise (aburu) nitori ki (Allahu) le fi (iya) apa kan eyi ti won se nise (aburu) to won lenu wo nitori ki won le seri pada (nibi aburu)
قُلْ سِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَانْظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ مِنْ قَبْلُ ۚ كَانَ أَكْثَرُهُمْ مُشْرِكِينَ
So pe: “E rin lori ile, ki e wo bi atubotan awon t’o siwaju se ri! Opolopo won ni won je osebo.”
فَأَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ الْقَيِّمِ مِنْ قَبْلِ أَنْ يَأْتِيَ يَوْمٌ لَا مَرَدَّ لَهُ مِنَ اللَّهِ ۖ يَوْمَئِذٍ يَصَّدَّعُونَ
Nitori naa, doju re ko esin t’o feserinle siwaju ki ojo kan to de, ti ko si nnkan ti o le ye e lodo Allahu. Ni ojo yen ni awon eniyan yoo pinya si (ero Ogba Idera ati ero Ina)
مَنْ كَفَرَ فَعَلَيْهِ كُفْرُهُ ۖ وَمَنْ عَمِلَ صَالِحًا فَلِأَنْفُسِهِمْ يَمْهَدُونَ
Enikeni ti o ba sai gbagbo, ori ara re ni (iya) aigbagbo re wa. Enikeni ti o ba si se ise rere, emi ara won ni won n te ite (Ogba Idera) sile fun
لِيَجْزِيَ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ مِنْ فَضْلِهِ ۚ إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الْكَافِرِينَ
nitori ki (Allahu) le san esan rere ninu oore ajulo Re fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere. Dajudaju (Allahu) ko nifee awon alaigbagbo

Choose other languages: