Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #82 Translated in Yoruba

أَيْنَمَا تَكُونُوا يُدْرِكْكُمُ الْمَوْتُ وَلَوْ كُنْتُمْ فِي بُرُوجٍ مُشَيَّدَةٍ ۗ وَإِنْ تُصِبْهُمْ حَسَنَةٌ يَقُولُوا هَٰذِهِ مِنْ عِنْدِ اللَّهِ ۖ وَإِنْ تُصِبْهُمْ سَيِّئَةٌ يَقُولُوا هَٰذِهِ مِنْ عِنْدِكَ ۚ قُلْ كُلٌّ مِنْ عِنْدِ اللَّهِ ۖ فَمَالِ هَٰؤُلَاءِ الْقَوْمِ لَا يَكَادُونَ يَفْقَهُونَ حَدِيثًا
Ibikibi ti e ba wa, iku yoo pade yin, eyin ibaa wa ninu odi ile giga fiofio. Ti oore (ikogun) kan ba te won lowo, won a wi pe: “Eyi wa lati odo Allahu.” Ti aburu (ifogun) kan ba si sele si won, won a wi pe: “Eyi wa lati odo re.” So pe: “Gbogbo re wa lati odo Allahu.” Ki l’o n se awon eniyan wonyi na, ti won ko fee gbo agboye oro kan
مَا أَصَابَكَ مِنْ حَسَنَةٍ فَمِنَ اللَّهِ ۖ وَمَا أَصَابَكَ مِنْ سَيِّئَةٍ فَمِنْ نَفْسِكَ ۚ وَأَرْسَلْنَاكَ لِلنَّاسِ رَسُولًا ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ شَهِيدًا
Ohunkohun t’o ba te o lowo ninu oore, lati odo Allahu ni. Ohunkohun ti o ba si sele si o ninu aburu, lati odo ara re ni. A ran o nise pe ki o je Ojise fun awon eniyan. Allahu si to ni Elerii
مَنْ يُطِعِ الرَّسُولَ فَقَدْ أَطَاعَ اللَّهَ ۖ وَمَنْ تَوَلَّىٰ فَمَا أَرْسَلْنَاكَ عَلَيْهِمْ حَفِيظًا
Enikeni t’o ba tele Ojise naa, o ti tele (ase) Allahu. Enikeni t’o ba si peyinda, A o ran o nise oluso lori won
وَيَقُولُونَ طَاعَةٌ فَإِذَا بَرَزُوا مِنْ عِنْدِكَ بَيَّتَ طَائِفَةٌ مِنْهُمْ غَيْرَ الَّذِي تَقُولُ ۖ وَاللَّهُ يَكْتُبُ مَا يُبَيِّتُونَ ۖ فَأَعْرِضْ عَنْهُمْ وَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ وَكِيلًا
Won n wi pe: “A tele ase re.” Sugbon nigba ti won ba jade kuro lodo re, igun kan ninu won maa gbimo nnkan ti o yato si eyi ti n so (losan-an). Allahu si n se akosile ohun ti won n gbimo loru. Nitori naa, seri kuro lodo won, ki o si gbarale Allahu. Allahu si to Alaabo
أَفَلَا يَتَدَبَّرُونَ الْقُرْآنَ ۚ وَلَوْ كَانَ مِنْ عِنْدِ غَيْرِ اللَّهِ لَوَجَدُوا فِيهِ اخْتِلَافًا كَثِيرًا
Se won ko ronu nipa al-Ƙur’an ni? Ti o ba je pe o wa lati odo elomiiran yato si Allahu, won iba ri opolopo itakora ninu re

Choose other languages: