Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #83 Translated in Yoruba

مَا أَصَابَكَ مِنْ حَسَنَةٍ فَمِنَ اللَّهِ ۖ وَمَا أَصَابَكَ مِنْ سَيِّئَةٍ فَمِنْ نَفْسِكَ ۚ وَأَرْسَلْنَاكَ لِلنَّاسِ رَسُولًا ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ شَهِيدًا
Ohunkohun t’o ba te o lowo ninu oore, lati odo Allahu ni. Ohunkohun ti o ba si sele si o ninu aburu, lati odo ara re ni. A ran o nise pe ki o je Ojise fun awon eniyan. Allahu si to ni Elerii
مَنْ يُطِعِ الرَّسُولَ فَقَدْ أَطَاعَ اللَّهَ ۖ وَمَنْ تَوَلَّىٰ فَمَا أَرْسَلْنَاكَ عَلَيْهِمْ حَفِيظًا
Enikeni t’o ba tele Ojise naa, o ti tele (ase) Allahu. Enikeni t’o ba si peyinda, A o ran o nise oluso lori won
وَيَقُولُونَ طَاعَةٌ فَإِذَا بَرَزُوا مِنْ عِنْدِكَ بَيَّتَ طَائِفَةٌ مِنْهُمْ غَيْرَ الَّذِي تَقُولُ ۖ وَاللَّهُ يَكْتُبُ مَا يُبَيِّتُونَ ۖ فَأَعْرِضْ عَنْهُمْ وَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ وَكِيلًا
Won n wi pe: “A tele ase re.” Sugbon nigba ti won ba jade kuro lodo re, igun kan ninu won maa gbimo nnkan ti o yato si eyi ti n so (losan-an). Allahu si n se akosile ohun ti won n gbimo loru. Nitori naa, seri kuro lodo won, ki o si gbarale Allahu. Allahu si to Alaabo
أَفَلَا يَتَدَبَّرُونَ الْقُرْآنَ ۚ وَلَوْ كَانَ مِنْ عِنْدِ غَيْرِ اللَّهِ لَوَجَدُوا فِيهِ اخْتِلَافًا كَثِيرًا
Se won ko ronu nipa al-Ƙur’an ni? Ti o ba je pe o wa lati odo elomiiran yato si Allahu, won iba ri opolopo itakora ninu re
وَإِذَا جَاءَهُمْ أَمْرٌ مِنَ الْأَمْنِ أَوِ الْخَوْفِ أَذَاعُوا بِهِ ۖ وَلَوْ رَدُّوهُ إِلَى الرَّسُولِ وَإِلَىٰ أُولِي الْأَمْرِ مِنْهُمْ لَعَلِمَهُ الَّذِينَ يَسْتَنْبِطُونَهُ مِنْهُمْ ۗ وَلَوْلَا فَضْلُ اللَّهِ عَلَيْكُمْ وَرَحْمَتُهُ لَاتَّبَعْتُمُ الشَّيْطَانَ إِلَّا قَلِيلًا
Nigba ti oro ifayabale tabi ipaya kan ba de ba won, won si maa tan an kale. Ti o ba je pe won seri re si (oro) Ojise ati awon alase (iyen, awon onimo esin) ninu won, awon t’o n yo ododo jade ninu oro ninu won iba mo on. Ti ki i ba se oore ajulo Allahu ati aanu Re lori yin ni, eyin iba tele Esu afi iba die (ninu yin)

Choose other languages: