Surah An-Nisa Ayahs #14 Translated in Yoruba
إِنَّ الَّذِينَ يَأْكُلُونَ أَمْوَالَ الْيَتَامَىٰ ظُلْمًا إِنَّمَا يَأْكُلُونَ فِي بُطُونِهِمْ نَارًا ۖ وَسَيَصْلَوْنَ سَعِيرًا
Dajudaju awon t’o n je dukia omo orukan pelu abosi, Ina kuku ni won n je sinu ikun won. Won si maa wo inu Ina t’o n jo
يُوصِيكُمُ اللَّهُ فِي أَوْلَادِكُمْ ۖ لِلذَّكَرِ مِثْلُ حَظِّ الْأُنْثَيَيْنِ ۚ فَإِنْ كُنَّ نِسَاءً فَوْقَ اثْنَتَيْنِ فَلَهُنَّ ثُلُثَا مَا تَرَكَ ۖ وَإِنْ كَانَتْ وَاحِدَةً فَلَهَا النِّصْفُ ۚ وَلِأَبَوَيْهِ لِكُلِّ وَاحِدٍ مِنْهُمَا السُّدُسُ مِمَّا تَرَكَ إِنْ كَانَ لَهُ وَلَدٌ ۚ فَإِنْ لَمْ يَكُنْ لَهُ وَلَدٌ وَوَرِثَهُ أَبَوَاهُ فَلِأُمِّهِ الثُّلُثُ ۚ فَإِنْ كَانَ لَهُ إِخْوَةٌ فَلِأُمِّهِ السُّدُسُ ۚ مِنْ بَعْدِ وَصِيَّةٍ يُوصِي بِهَا أَوْ دَيْنٍ ۗ آبَاؤُكُمْ وَأَبْنَاؤُكُمْ لَا تَدْرُونَ أَيُّهُمْ أَقْرَبُ لَكُمْ نَفْعًا ۚ فَرِيضَةً مِنَ اللَّهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمًا
Allahu n pase fun yin nipa (ogun ti e maa pin fun) awon omo yin; ti okunrin ni iru ipin ti obinrin meji. Ti won ba si je obinrin (nikan) meji soke, tiwon ni ida meji ninu ida meta ohun ti (oku) fi sile. Ti o ba je obinrin kan soso, idaji ni tire. Ti obi re mejeeji, ida kan ninu ida mefa ni ti ikookan awon mejeeji ninu ohun ti oku fi sile, ti o ba ni omo laye. Ti ko ba si ni omo laye, ti o si je pe awon obi re mejeeji l’o maa jogun re, ida kan ninu ida meta ni ti iya re. Ti o ba ni arakunrin (tabi arabinrin), ida kan ninu ida mefa ni ti iya re, (gbogbo re) leyin asoole ti o so tabi gbese. Awon baba yin ati awon omokunrin yin; eyin ko mo ewo ninu won lo maa mu anfaani ba yin julo. (Ipin) oran-anyan ni lati odo Allahu. Dajudaju Allahu n je Onimo, Ologbon
وَلَكُمْ نِصْفُ مَا تَرَكَ أَزْوَاجُكُمْ إِنْ لَمْ يَكُنْ لَهُنَّ وَلَدٌ ۚ فَإِنْ كَانَ لَهُنَّ وَلَدٌ فَلَكُمُ الرُّبُعُ مِمَّا تَرَكْنَ ۚ مِنْ بَعْدِ وَصِيَّةٍ يُوصِينَ بِهَا أَوْ دَيْنٍ ۚ وَلَهُنَّ الرُّبُعُ مِمَّا تَرَكْتُمْ إِنْ لَمْ يَكُنْ لَكُمْ وَلَدٌ ۚ فَإِنْ كَانَ لَكُمْ وَلَدٌ فَلَهُنَّ الثُّمُنُ مِمَّا تَرَكْتُمْ ۚ مِنْ بَعْدِ وَصِيَّةٍ تُوصُونَ بِهَا أَوْ دَيْنٍ ۗ وَإِنْ كَانَ رَجُلٌ يُورَثُ كَلَالَةً أَوِ امْرَأَةٌ وَلَهُ أَخٌ أَوْ أُخْتٌ فَلِكُلِّ وَاحِدٍ مِنْهُمَا السُّدُسُ ۚ فَإِنْ كَانُوا أَكْثَرَ مِنْ ذَٰلِكَ فَهُمْ شُرَكَاءُ فِي الثُّلُثِ ۚ مِنْ بَعْدِ وَصِيَّةٍ يُوصَىٰ بِهَا أَوْ دَيْنٍ غَيْرَ مُضَارٍّ ۚ وَصِيَّةً مِنَ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَلِيمٌ
Tiyin ni ilaji ohun ti awon iyawo yin fi sile, ti won ko ba ni omo. Ti won ba si ni omo, tiyin ni ida kan ninu ida merin ohun ti won fi sile, leyin asoole ti won so tabi gbese. Tiwon si ni ida kan ninu ida merin ohun ti e fi sile, ti eyin ko ba ni omo laye. Ti e ba ni omo laye, ida kan ninu ida mejo ni tiwon ninu ohun ti e fi sile leyin asoole ti e so tabi gbese. Ti okunrin kan tabi obinrin kan ti won fe jogun re ko ba ni obi ati omo, ti o si ni arakunrin kan tabi arabinrin kan, ida kan ninu ida mefa ni ti ikookan awon mejeeji. Ti won ba si po ju bee lo, won yoo dijo pin ida kan ninu ida meta, leyin asoole ti won so tabi gbese, ti ko nii je ipalara. Ofin kan ni lati odo Allahu. Allahu si ni Onimo, Alafarada
تِلْكَ حُدُودُ اللَّهِ ۚ وَمَنْ يُطِعِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ يُدْخِلْهُ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ وَذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ
Iyen ni awon enu-ala (ti) Allahu (gbekale fun ogun pipin). Enikeni ti o ba si tele ti Allahu ati Ojise Re, (Allahu) yoo mu un wo inu awon Ogba Idera kan ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Iyen si ni erenje nla
وَمَنْ يَعْصِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَيَتَعَدَّ حُدُودَهُ يُدْخِلْهُ نَارًا خَالِدًا فِيهَا وَلَهُ عَذَابٌ مُهِينٌ
Enikeni ti o ba si yapa (ase) Allahu ati Ojise Re, ti o si n tayo awon enu-ala ti Allahu gbekale, (Allahu) yoo mu un wo inu Ina kan. Olusegbere ni ninu re. Iya ti i yepere eda si n be fun un
Choose other languages:

Albanian

Amharic

Azerbaijani

Bengali

Bosnian

Bulgarian

Burmese

Chinese

Danish

Dutch

English

Farsi

Filipino

French

Fulah

German

Gujarati

Hausa

Hindi

Indonesian

Italian

Japanese

Jawa

Kazakh

Khmer

Korean

Kurdish

Kyrgyz

Malay

Malayalam

Norwegian

Pashto

Persian

Polish

Portuguese

Punjabi

Russian

Sindhi

Sinhalese

Somali

Spanish

Swahili

Swedish

Tajik

Tamil

Tatar

Telugu

Thai

Turkish

Urdu

Uyghur

Uzbek

Vietnamese

Yoruba
