Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Mumtahana Ayahs #8 Translated in Yoruba

قَدْ كَانَتْ لَكُمْ أُسْوَةٌ حَسَنَةٌ فِي إِبْرَاهِيمَ وَالَّذِينَ مَعَهُ إِذْ قَالُوا لِقَوْمِهِمْ إِنَّا بُرَآءُ مِنْكُمْ وَمِمَّا تَعْبُدُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ كَفَرْنَا بِكُمْ وَبَدَا بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمُ الْعَدَاوَةُ وَالْبَغْضَاءُ أَبَدًا حَتَّىٰ تُؤْمِنُوا بِاللَّهِ وَحْدَهُ إِلَّا قَوْلَ إِبْرَاهِيمَ لِأَبِيهِ لَأَسْتَغْفِرَنَّ لَكَ وَمَا أَمْلِكُ لَكَ مِنَ اللَّهِ مِنْ شَيْءٍ ۖ رَبَّنَا عَلَيْكَ تَوَكَّلْنَا وَإِلَيْكَ أَنَبْنَا وَإِلَيْكَ الْمَصِيرُ
Dajudaju awokose rere ti wa fun yin ni ara (Anabi) ’Ibrohim ati awon t’o wa pelu re. Nigba ti won so fun ijo won pe: "Dajudaju awa yowo-yose kuro ninu oro yin ati ohun ti e n josin fun leyin Allahu. A tako yin. Ota ati ikorira si ti han laaarin wa titi laelae ayafi igba ti e ba to gbagbo ninu Allahu nikan soso. - Afi oro ti (Anabi) ’Ibrohim so fun baba re pe: "Dajudaju mo maa toro aforijin fun o, emi ko si ni ikapa kini kan fun o lodo Allahu. - Oluwa wa, Iwo l’a gbarale. Odo Re l’a seri pada si (nipa ironupiwada). Odo Re si ni abo eda
رَبَّنَا لَا تَجْعَلْنَا فِتْنَةً لِلَّذِينَ كَفَرُوا وَاغْفِرْ لَنَا رَبَّنَا ۖ إِنَّكَ أَنْتَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Oluwa wa, ma se wa ni adanwo fun awon t’o sai gbagbo. Forijin wa, Oluwa wa. Dajudaju Iwo ni Alagbara, Ologbon
لَقَدْ كَانَ لَكُمْ فِيهِمْ أُسْوَةٌ حَسَنَةٌ لِمَنْ كَانَ يَرْجُو اللَّهَ وَالْيَوْمَ الْآخِرَ ۚ وَمَنْ يَتَوَلَّ فَإِنَّ اللَّهَ هُوَ الْغَنِيُّ الْحَمِيدُ
Dajudaju awokose rere ti wa fun yin ni ara won fun eni t’o n reti (esan) Allahu ati Ojo Ikeyin. Enikeni ti o ba peyin da, dajudaju Allahu, Oun ni Oloro, Eleyin
عَسَى اللَّهُ أَنْ يَجْعَلَ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَ الَّذِينَ عَادَيْتُمْ مِنْهُمْ مَوَدَّةً ۚ وَاللَّهُ قَدِيرٌ ۚ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ
O le je pe Allahu yoo fi ife si aarin eyin ati awon ti e mu ni ota ninu won (iyen, nigba ti won ba di musulumi). Allahu ni Alagbara. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun
لَا يَنْهَاكُمُ اللَّهُ عَنِ الَّذِينَ لَمْ يُقَاتِلُوكُمْ فِي الدِّينِ وَلَمْ يُخْرِجُوكُمْ مِنْ دِيَارِكُمْ أَنْ تَبَرُّوهُمْ وَتُقْسِطُوا إِلَيْهِمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُقْسِطِينَ
Allahu ko ko fun yin nipa awon ti ko gbe ogun ti yin nipa esin, ti won ko si le yin jade kuro ninu ilu yin, pe ki e se daadaa si won, ki e si se deede si won. Dajudaju Allahu feran awon oluse-deede

Choose other languages: