Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Maeda Ayahs #100 Translated in Yoruba

أُحِلَّ لَكُمْ صَيْدُ الْبَحْرِ وَطَعَامُهُ مَتَاعًا لَكُمْ وَلِلسَّيَّارَةِ ۖ وَحُرِّمَ عَلَيْكُمْ صَيْدُ الْبَرِّ مَا دُمْتُمْ حُرُمًا ۗ وَاتَّقُوا اللَّهَ الَّذِي إِلَيْهِ تُحْشَرُونَ
Won se odo dide ati jije ounje (okunbete) inu re ni eto fun yin. Nnkan igbadun ni fun eyin ati awon onirin-ajo. Won si se igbe dide ni eewo fun yin nigba ti e ba wa ninu aso hurumi. E beru Allahu, Eni ti won maa ko yin jo si odo Re
جَعَلَ اللَّهُ الْكَعْبَةَ الْبَيْتَ الْحَرَامَ قِيَامًا لِلنَّاسِ وَالشَّهْرَ الْحَرَامَ وَالْهَدْيَ وَالْقَلَائِدَ ۚ ذَٰلِكَ لِتَعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ وَأَنَّ اللَّهَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ
Allahu se Kaaba, Ile Haram, ni aye aabo fun awon eniyan. (Nnkan aabo naa ni) awon osu owo, awon eran ore (ti won ko sami si lorun) ati (awon eran ore) ti won sami si lorun. Iyen ri bee ki e le mo pe dajudaju Allahu mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Ati pe dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan
اعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ وَأَنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ
E mo pe dajudaju Allahu le nibi iya. Ati pe dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun
مَا عَلَى الرَّسُولِ إِلَّا الْبَلَاغُ ۗ وَاللَّهُ يَعْلَمُ مَا تُبْدُونَ وَمَا تَكْتُمُونَ
Ko si ojuse kan fun Ojise naa bi ko se ise-jije. Allahu si mo ohun ti e n safi han re ati ohun ti e n fi pamo
قُلْ لَا يَسْتَوِي الْخَبِيثُ وَالطَّيِّبُ وَلَوْ أَعْجَبَكَ كَثْرَةُ الْخَبِيثِ ۚ فَاتَّقُوا اللَّهَ يَا أُولِي الْأَلْبَابِ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ
So pe: “Ohun buruku ati ohun daadaa ko dogba, pupo ohun buruku ibaa jo o loju”. Nitori naa, e beru Allahu, eyin onilaakaye, nitori ki e le jere.”

Choose other languages: