Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Maeda Ayahs #65 Translated in Yoruba

وَإِذَا جَاءُوكُمْ قَالُوا آمَنَّا وَقَدْ دَخَلُوا بِالْكُفْرِ وَهُمْ قَدْ خَرَجُوا بِهِ ۚ وَاللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا كَانُوا يَكْتُمُونَ
Nigba ti won ba wa si odo yin, won a wi pe: “A gbagbo.” Dajudaju won wole (ti yin) pelu aigbagbo, won si ti jade pelu re. Allahu si nimo julo nipa ohun ti won n fi pamo
وَتَرَىٰ كَثِيرًا مِنْهُمْ يُسَارِعُونَ فِي الْإِثْمِ وَالْعُدْوَانِ وَأَكْلِهِمُ السُّحْتَ ۚ لَبِئْسَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
O maa ri opolopo ninu won, ti won n yara ko sinu ese, itayo enu-ala ati jije ti won n je owo eru. Dajudaju ohun ti won n se nise buru
لَوْلَا يَنْهَاهُمُ الرَّبَّانِيُّونَ وَالْأَحْبَارُ عَنْ قَوْلِهِمُ الْإِثْمَ وَأَكْلِهِمُ السُّحْتَ ۚ لَبِئْسَ مَا كَانُوا يَصْنَعُونَ
Ki ni ko je ki awon alufaa ati awon amofin maa ko fun won nipa oro enu won (ti o je) ese ati jije ti won n je owo eru! Dajudaju ohun ti won n se nise buru
وَقَالَتِ الْيَهُودُ يَدُ اللَّهِ مَغْلُولَةٌ ۚ غُلَّتْ أَيْدِيهِمْ وَلُعِنُوا بِمَا قَالُوا ۘ بَلْ يَدَاهُ مَبْسُوطَتَانِ يُنْفِقُ كَيْفَ يَشَاءُ ۚ وَلَيَزِيدَنَّ كَثِيرًا مِنْهُمْ مَا أُنْزِلَ إِلَيْكَ مِنْ رَبِّكَ طُغْيَانًا وَكُفْرًا ۚ وَأَلْقَيْنَا بَيْنَهُمُ الْعَدَاوَةَ وَالْبَغْضَاءَ إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ ۚ كُلَّمَا أَوْقَدُوا نَارًا لِلْحَرْبِ أَطْفَأَهَا اللَّهُ ۚ وَيَسْعَوْنَ فِي الْأَرْضِ فَسَادًا ۚ وَاللَّهُ لَا يُحِبُّ الْمُفْسِدِينَ
Awon yehudi wi pe: "Owo Allahu wa ni didi pa." A di owo won pa. A si sebi le won nitori ohun ti won wi. Amo owo Re mejeeji wa ni tite sile. O si n tore bi O se fe. Ohun ti won sokale fun o lati odo Oluwa Re yoo kuku je ki opolopo won lekun ni igberaga ati aigbagbo ni. A si ju ota ati ikorira saaarin won titi di Ojo Ajinde. Igbakigba ti won ba dana ogun, Allahu si maa pana re. Won si n se ibaje lori ile. Allahu ko si nifee awon obileje
وَلَوْ أَنَّ أَهْلَ الْكِتَابِ آمَنُوا وَاتَّقَوْا لَكَفَّرْنَا عَنْهُمْ سَيِّئَاتِهِمْ وَلَأَدْخَلْنَاهُمْ جَنَّاتِ النَّعِيمِ
Ti o ba je pe dajudaju awon ahlul-kitab gbagbo ni ododo, ki won si beru (Allahu), Awa iba pa awon aida won re fun won, Awa iba si mu won wo inu awon Ogba Idera

Choose other languages: