Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hashr Ayahs #14 Translated in Yoruba

وَالَّذِينَ جَاءُوا مِنْ بَعْدِهِمْ يَقُولُونَ رَبَّنَا اغْفِرْ لَنَا وَلِإِخْوَانِنَا الَّذِينَ سَبَقُونَا بِالْإِيمَانِ وَلَا تَجْعَلْ فِي قُلُوبِنَا غِلًّا لِلَّذِينَ آمَنُوا رَبَّنَا إِنَّكَ رَءُوفٌ رَحِيمٌ
Awon t’o de leyin won n so pe: "Oluwa wa, forijin awa ati awon omo iya wa t’o siwaju wa ninu igbagbo ododo. Ma se je ki inunibini wa ninu okan wa si awon t’o gbagbo ni ododo. Oluwa wa, dajudaju Iwo ni Alaaanu, Asake-orun
أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِينَ نَافَقُوا يَقُولُونَ لِإِخْوَانِهِمُ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ لَئِنْ أُخْرِجْتُمْ لَنَخْرُجَنَّ مَعَكُمْ وَلَا نُطِيعُ فِيكُمْ أَحَدًا أَبَدًا وَإِنْ قُوتِلْتُمْ لَنَنْصُرَنَّكُمْ وَاللَّهُ يَشْهَدُ إِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ
Se o o ri awon t’o sobe-selu ti won n wi fun awon omo iya won, awon t’o sai gbagbo ninu awon ahlul-kitab, pe "Dajudaju ti won ba le yin jade (kuro ninu ilu), awa naa gbodo jade pelu yin ni. Awa ko si nii tele ase eni kan lori yin laelae. Ti won ba si gbe ogun dide si yin, awa gbodo se iranlowo fun yin ni." Allahu si n jerii pe dajudaju opuro ni won
لَئِنْ أُخْرِجُوا لَا يَخْرُجُونَ مَعَهُمْ وَلَئِنْ قُوتِلُوا لَا يَنْصُرُونَهُمْ وَلَئِنْ نَصَرُوهُمْ لَيُوَلُّنَّ الْأَدْبَارَ ثُمَّ لَا يُنْصَرُونَ
Dajudaju ti won ba le won jade, won ko nii jade pelu won. Dajudaju ti won ba si gbogun ti won, won ko nii se iranlowo fun won. Ti won ba si wa iranlowo won, dajudaju won yoo peyin da (lati fese fee). Leyin naa, won ko si nii ran won lowo
لَأَنْتُمْ أَشَدُّ رَهْبَةً فِي صُدُورِهِمْ مِنَ اللَّهِ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَا يَفْقَهُونَ
Dajudaju eyin ni erujeje t’o lagbara ju Allahu lo ninu igba-aya won. Iyen nitori pe dajudaju awon ni ijo ti ko gbo agboye
لَا يُقَاتِلُونَكُمْ جَمِيعًا إِلَّا فِي قُرًى مُحَصَّنَةٍ أَوْ مِنْ وَرَاءِ جُدُرٍ ۚ بَأْسُهُمْ بَيْنَهُمْ شَدِيدٌ ۚ تَحْسَبُهُمْ جَمِيعًا وَقُلُوبُهُمْ شَتَّىٰ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَا يَعْقِلُونَ
Won ko le parapo doju ija ko yin afi (ki won) wa ninu odi ilu tabi (ki won wa) leyin awon ogiri. Ogun aarin ara won gan-an le. O n lero pe won wa ni irepo ni, otooto si ni okan won wa. Iyen nitori pe dajudaju awon ni ijo ti ko ni laakaye

Choose other languages: