Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hajj Ayahs #46 Translated in Yoruba

وَإِنْ يُكَذِّبُوكَ فَقَدْ كَذَّبَتْ قَبْلَهُمْ قَوْمُ نُوحٍ وَعَادٌ وَثَمُودُ
Ti won ba pe o ni opuro, awon ijo Nuh, ijo ‘Ad ati ijo Thamud kuku ti pe awon Ojise won ni opuro siwaju won
وَقَوْمُ إِبْرَاهِيمَ وَقَوْمُ لُوطٍ
Ati pe ijo ’Ibrohim ati ijo (Anabi) Lut
وَأَصْحَابُ مَدْيَنَ ۖ وَكُذِّبَ مُوسَىٰ فَأَمْلَيْتُ لِلْكَافِرِينَ ثُمَّ أَخَذْتُهُمْ ۖ فَكَيْفَ كَانَ نَكِيرِ
ati awon ara ilu Modyan (awon naa se bee). Won tun pe (Anabi) Musa ni opuro. Mo si lo awon alaigbagbo lara. Leyin naa, Mo gba won mu. Bawo si ni bi Mo se (fi iya) ko (aburu fun won) ti ri
فَكَأَيِّنْ مِنْ قَرْيَةٍ أَهْلَكْنَاهَا وَهِيَ ظَالِمَةٌ فَهِيَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا وَبِئْرٍ مُعَطَّلَةٍ وَقَصْرٍ مَشِيدٍ
Nitori naa, meloo meloo ninu ilu ti A ti pare nigba ti won je alabosi; awon ile won dawo lule pelu orule re. (Meloo meloo ninu) kannga ti won ti pati (nipase iparun) ati ile peteesi onibiriki (t’o ti dahoro)
أَفَلَمْ يَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَتَكُونَ لَهُمْ قُلُوبٌ يَعْقِلُونَ بِهَا أَوْ آذَانٌ يَسْمَعُونَ بِهَا ۖ فَإِنَّهَا لَا تَعْمَى الْأَبْصَارُ وَلَٰكِنْ تَعْمَى الْقُلُوبُ الَّتِي فِي الصُّدُورِ
Se won ko rin kiri lori ile ki won si ni awon okan ti won maa fi se laakaye tabi awon eti ti won maa fi gboro? Dajudaju awon oju ko fo, sugbon awon okan t’o wa ninu igba-aya l’o n fo

Choose other languages: