Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #101 Translated in Yoruba

قُلْ مَنْ كَانَ عَدُوًّا لِجِبْرِيلَ فَإِنَّهُ نَزَّلَهُ عَلَىٰ قَلْبِكَ بِإِذْنِ اللَّهِ مُصَدِّقًا لِمَا بَيْنَ يَدَيْهِ وَهُدًى وَبُشْرَىٰ لِلْمُؤْمِنِينَ
So pe: “Enikeni ti o ba je ota fun (molaika) Jibril, (o ti di ota Allahu) nitori pe dajudaju (molaika) Jibril lo mu al-Ƙur’an wa sinu okan re pelu ase Allahu. Al-Ƙur’an si n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa siwaju re. O je imona ati idunnu fun awon onigbagbo ododo
مَنْ كَانَ عَدُوًّا لِلَّهِ وَمَلَائِكَتِهِ وَرُسُلِهِ وَجِبْرِيلَ وَمِيكَالَ فَإِنَّ اللَّهَ عَدُوٌّ لِلْكَافِرِينَ
Enikeni ti o ba je ota fun Allahu, awon molaika Re, awon Ojise Re, Jibril ati Mikal, dajudaju Allahu ni ota fun awon alaigbagbo
وَلَقَدْ أَنْزَلْنَا إِلَيْكَ آيَاتٍ بَيِّنَاتٍ ۖ وَمَا يَكْفُرُ بِهَا إِلَّا الْفَاسِقُونَ
Dajudaju A ti so awon ayah to yanju kale fun o. Eni kan ko nii sai gbagbo ninu re ayafi awon arufin
أَوَكُلَّمَا عَاهَدُوا عَهْدًا نَبَذَهُ فَرِيقٌ مِنْهُمْ ۚ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ
Ati pe se gbogbo igba ti won ba da majemu kan ni apa kan ninu won yoo maa ju u nu? Rara, opolopo won ni ko gbagbo
وَلَمَّا جَاءَهُمْ رَسُولٌ مِنْ عِنْدِ اللَّهِ مُصَدِّقٌ لِمَا مَعَهُمْ نَبَذَ فَرِيقٌ مِنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ كِتَابَ اللَّهِ وَرَاءَ ظُهُورِهِمْ كَأَنَّهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
Ati pe nigba ti Ojise kan lati odo Allahu de ba won, ti o n jerii si eyi t’o je ododo ninu ohun t’o wa pelu won, apa kan ninu awon ti A fun ni Tira gbe Tira Allahu ju s’eyin leyin won bi eni pe won ko mo (pe asoole nipa Anabi s.a.w. wa ninu re)

Choose other languages: