Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #99 Translated in Yoruba

وَلَنْ يَتَمَنَّوْهُ أَبَدًا بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيهِمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِالظَّالِمِينَ
Won ko nii toro iku laelae nitori ohun ti owo won ti siwaju. Allahu si ni Onimo nipa awon alabosi
وَلَتَجِدَنَّهُمْ أَحْرَصَ النَّاسِ عَلَىٰ حَيَاةٍ وَمِنَ الَّذِينَ أَشْرَكُوا ۚ يَوَدُّ أَحَدُهُمْ لَوْ يُعَمَّرُ أَلْفَ سَنَةٍ وَمَا هُوَ بِمُزَحْزِحِهِ مِنَ الْعَذَابِ أَنْ يُعَمَّرَ ۗ وَاللَّهُ بَصِيرٌ بِمَا يَعْمَلُونَ
Dajudaju o maa ri won pe awon ni eniyan t’o l’oju kokoro julo nipa isemi aye, (won tun l’oju kokoro ju) awon osebo lo. Ikookan won n fe pe ti A ba le fun oun ni egberun odun lo laye. Bee si ni, ki i se ohun ti o maa la a ninu iya ni pe ki A fun un ni isemi gigun lo. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti won n se nise
قُلْ مَنْ كَانَ عَدُوًّا لِجِبْرِيلَ فَإِنَّهُ نَزَّلَهُ عَلَىٰ قَلْبِكَ بِإِذْنِ اللَّهِ مُصَدِّقًا لِمَا بَيْنَ يَدَيْهِ وَهُدًى وَبُشْرَىٰ لِلْمُؤْمِنِينَ
So pe: “Enikeni ti o ba je ota fun (molaika) Jibril, (o ti di ota Allahu) nitori pe dajudaju (molaika) Jibril lo mu al-Ƙur’an wa sinu okan re pelu ase Allahu. Al-Ƙur’an si n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa siwaju re. O je imona ati idunnu fun awon onigbagbo ododo
مَنْ كَانَ عَدُوًّا لِلَّهِ وَمَلَائِكَتِهِ وَرُسُلِهِ وَجِبْرِيلَ وَمِيكَالَ فَإِنَّ اللَّهَ عَدُوٌّ لِلْكَافِرِينَ
Enikeni ti o ba je ota fun Allahu, awon molaika Re, awon Ojise Re, Jibril ati Mikal, dajudaju Allahu ni ota fun awon alaigbagbo
وَلَقَدْ أَنْزَلْنَا إِلَيْكَ آيَاتٍ بَيِّنَاتٍ ۖ وَمَا يَكْفُرُ بِهَا إِلَّا الْفَاسِقُونَ
Dajudaju A ti so awon ayah to yanju kale fun o. Eni kan ko nii sai gbagbo ninu re ayafi awon arufin

Choose other languages: