Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #60 Translated in Yoruba

ثُمَّ بَعَثْنَاكُمْ مِنْ بَعْدِ مَوْتِكُمْ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Leyin naa, A ji yin dide leyin iku yin, nitori ki e le dupe (fun Allahu)
وَظَلَّلْنَا عَلَيْكُمُ الْغَمَامَ وَأَنْزَلْنَا عَلَيْكُمُ الْمَنَّ وَالسَّلْوَىٰ ۖ كُلُوا مِنْ طَيِّبَاتِ مَا رَزَقْنَاكُمْ ۖ وَمَا ظَلَمُونَا وَلَٰكِنْ كَانُوا أَنْفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
A tun fi esujo se iboji fun yin. A si tun so (ohun mimu) monnu ati (ohun jije) salwa kale fun yin. E je ninu awon nnkan daadaa ti A pese fun yin. Won ko si sabosi si Wa, sugbon emi ara won ni won n sabosi si
وَإِذْ قُلْنَا ادْخُلُوا هَٰذِهِ الْقَرْيَةَ فَكُلُوا مِنْهَا حَيْثُ شِئْتُمْ رَغَدًا وَادْخُلُوا الْبَابَ سُجَّدًا وَقُولُوا حِطَّةٌ نَغْفِرْ لَكُمْ خَطَايَاكُمْ ۚ وَسَنَزِيدُ الْمُحْسِنِينَ
(E ranti) nigba ti A so pe: “E wo inu ilu yii. E je ninu ilu naa nibikibi ti e ba fe ni gbedemuke. E gba enu-ona ilu wole ni oluteriba. Ki e si wi pe: “Ha ese wa danu.” A oo fori awon ese yin jin yin. A o si se alekun (esan rere) fun awon oluse-rere
فَبَدَّلَ الَّذِينَ ظَلَمُوا قَوْلًا غَيْرَ الَّذِي قِيلَ لَهُمْ فَأَنْزَلْنَا عَلَى الَّذِينَ ظَلَمُوا رِجْزًا مِنَ السَّمَاءِ بِمَا كَانُوا يَفْسُقُونَ
Awon t’o sabosi yi oro naa pada (si nnkan miiran) yato si eyi ti A so fun won. Nitori naa, A so iya kale lati sanmo le awon t’o sabosi lori nitori pe won n ru ofin
وَإِذِ اسْتَسْقَىٰ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ فَقُلْنَا اضْرِبْ بِعَصَاكَ الْحَجَرَ ۖ فَانْفَجَرَتْ مِنْهُ اثْنَتَا عَشْرَةَ عَيْنًا ۖ قَدْ عَلِمَ كُلُّ أُنَاسٍ مَشْرَبَهُمْ ۖ كُلُوا وَاشْرَبُوا مِنْ رِزْقِ اللَّهِ وَلَا تَعْثَوْا فِي الْأَرْضِ مُفْسِدِينَ
(E ranti) nigba ti (Anabi) Musa toro omi fun ijo re. A si so pe: “Fi opa re na okuta.” Orisun omi mejila si san jade lati inu re. Iran kookan si ti mo ibumu won. E je, ki e si mu ninu arisiki Allahu. E ma bale je ni ti obileje

Choose other languages: