Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #53 Translated in Yoruba

وَإِذْ نَجَّيْنَاكُمْ مِنْ آلِ فِرْعَوْنَ يَسُومُونَكُمْ سُوءَ الْعَذَابِ يُذَبِّحُونَ أَبْنَاءَكُمْ وَيَسْتَحْيُونَ نِسَاءَكُمْ ۚ وَفِي ذَٰلِكُمْ بَلَاءٌ مِنْ رَبِّكُمْ عَظِيمٌ
(E ranti) nigba ti A gba yin la lowo awon eniyan Fir‘aon, ti won n fi iya buruku je yin, ti won n dunbu awon omokunrin yin, ti won si n je ki awon obinrin yin semi. Adanwo nla wa ninu iyen fun yin lati odo Oluwa yin
وَإِذْ فَرَقْنَا بِكُمُ الْبَحْرَ فَأَنْجَيْنَاكُمْ وَأَغْرَقْنَا آلَ فِرْعَوْنَ وَأَنْتُمْ تَنْظُرُونَ
(E ranti) nigba ti A pin agbami odo si otooto fun yin, A si gba yin la. A te awon eniyan Fir‘aon ri. Eyin naa si n wo (won ninu agbami odo)
وَإِذْ وَاعَدْنَا مُوسَىٰ أَرْبَعِينَ لَيْلَةً ثُمَّ اتَّخَذْتُمُ الْعِجْلَ مِنْ بَعْدِهِ وَأَنْتُمْ ظَالِمُونَ
(E ranti) nigba ti A se adehun ogoji oru fun (Anabi) Musa. Leyin naa, e tun bo oborogidi omo maalu leyin re. Alabosi si ni yin
ثُمَّ عَفَوْنَا عَنْكُمْ مِنْ بَعْدِ ذَٰلِكَ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Leyin naa, A moju kuro fun yin leyin iyen nitori ki e le dupe (fun Allahu)
وَإِذْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ وَالْفُرْقَانَ لَعَلَّكُمْ تَهْتَدُونَ
(E ranti) nigba ti A fun (Anabi) Musa ni Tira ati oro-ipinya nitori ki e le mona

Choose other languages: