Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #37 Translated in Yoruba

قَالَ يَا آدَمُ أَنْبِئْهُمْ بِأَسْمَائِهِمْ ۖ فَلَمَّا أَنْبَأَهُمْ بِأَسْمَائِهِمْ قَالَ أَلَمْ أَقُلْ لَكُمْ إِنِّي أَعْلَمُ غَيْبَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَأَعْلَمُ مَا تُبْدُونَ وَمَا كُنْتُمْ تَكْتُمُونَ
O so pe: “Adam, so oruko won fun won.” Nigba ti o so oruko won fun won tan, O so pe: “Se Emi ko so fun yin pe dajudaju Emi nimo ikoko awon sanmo ati ile, Mo si nimo ohun ti e n se afihan re ati ohun ti e n fi pamo?”
وَإِذْ قُلْنَا لِلْمَلَائِكَةِ اسْجُدُوا لِآدَمَ فَسَجَدُوا إِلَّا إِبْلِيسَ أَبَىٰ وَاسْتَكْبَرَ وَكَانَ مِنَ الْكَافِرِينَ
(Ranti) nigba ti A so fun awon molaika pe: “E fori kanle ki (Anabi) Adam.” Won si fori kanle ki i ayafi ’Iblis. O ko, o si se igberaga. O si wa ninu awon alaigbagbo
وَقُلْنَا يَا آدَمُ اسْكُنْ أَنْتَ وَزَوْجُكَ الْجَنَّةَ وَكُلَا مِنْهَا رَغَدًا حَيْثُ شِئْتُمَا وَلَا تَقْرَبَا هَٰذِهِ الشَّجَرَةَ فَتَكُونَا مِنَ الظَّالِمِينَ
A si so pe: “Adam, iwo ati iyawo re, e maa gbe ninu Ogba Idera. Ki e maa je ninu re ni gbedemuke ni ibikibi ti e ba fe. Ki e si ma se sunmo igi yii, ki e ma baa wa ninu awon alabosi.”
فَأَزَلَّهُمَا الشَّيْطَانُ عَنْهَا فَأَخْرَجَهُمَا مِمَّا كَانَا فِيهِ ۖ وَقُلْنَا اهْبِطُوا بَعْضُكُمْ لِبَعْضٍ عَدُوٌّ ۖ وَلَكُمْ فِي الْأَرْضِ مُسْتَقَرٌّ وَمَتَاعٌ إِلَىٰ حِينٍ
Amo Esu ye awon mejeeji lese kuro ninu Ogba Idera, o si mu won jade kuro ninu ibi ti won wa. A si so pe: "E sokale, ota ni apa kan yin je fun apa kan. Ibugbe ati nnkan igbadun si n be fun yin lori ile fun igba (die).”
فَتَلَقَّىٰ آدَمُ مِنْ رَبِّهِ كَلِمَاتٍ فَتَابَ عَلَيْهِ ۚ إِنَّهُ هُوَ التَّوَّابُ الرَّحِيمُ
Leyin naa, (Anabi) Adam ri awon oro kan gba lati odo Oluwa re. O si gba ironupiwada re. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun

Choose other languages: