Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #254 Translated in Yoruba

وَلَمَّا بَرَزُوا لِجَالُوتَ وَجُنُودِهِ قَالُوا رَبَّنَا أَفْرِغْ عَلَيْنَا صَبْرًا وَثَبِّتْ أَقْدَامَنَا وَانْصُرْنَا عَلَى الْقَوْمِ الْكَافِرِينَ
Nigba ti won jade si Jalut ati awon omo ogun re, won so pe: "Oluwa wa, fun wa ni omi suuru mu, fi ese wa rinle sinsin, ki O si ran wa lowo lori ijo alaigbagbo
فَهَزَمُوهُمْ بِإِذْنِ اللَّهِ وَقَتَلَ دَاوُودُ جَالُوتَ وَآتَاهُ اللَّهُ الْمُلْكَ وَالْحِكْمَةَ وَعَلَّمَهُ مِمَّا يَشَاءُ ۗ وَلَوْلَا دَفْعُ اللَّهِ النَّاسَ بَعْضَهُمْ بِبَعْضٍ لَفَسَدَتِ الْأَرْضُ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ ذُو فَضْلٍ عَلَى الْعَالَمِينَ
Won si segun won pelu iyonda Allahu. Dawud si pa Jalut. Allahu si fun un ni ijoba ati ogbon. O tun fi imo mo on ninu ohun ti O ba fe. Ti ko ba je pe Allahu n dena (aburu) fun awon eniyan ni, ti O n fi apa kan won dena (aburu) fun apa kan, ori ile iba ti baje. Sugbon Allahu ni Oloore ajulo lori gbogbo eda
تِلْكَ آيَاتُ اللَّهِ نَتْلُوهَا عَلَيْكَ بِالْحَقِّ ۚ وَإِنَّكَ لَمِنَ الْمُرْسَلِينَ
Iwonyi ni awon ayah Allahu, ti A n ke e fun o pelu ododo. Ati pe dajudaju iwo wa lara awon Ojise
تِلْكَ الرُّسُلُ فَضَّلْنَا بَعْضَهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ ۘ مِنْهُمْ مَنْ كَلَّمَ اللَّهُ ۖ وَرَفَعَ بَعْضَهُمْ دَرَجَاتٍ ۚ وَآتَيْنَا عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ الْبَيِّنَاتِ وَأَيَّدْنَاهُ بِرُوحِ الْقُدُسِ ۗ وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ مَا اقْتَتَلَ الَّذِينَ مِنْ بَعْدِهِمْ مِنْ بَعْدِ مَا جَاءَتْهُمُ الْبَيِّنَاتُ وَلَٰكِنِ اخْتَلَفُوا فَمِنْهُمْ مَنْ آمَنَ وَمِنْهُمْ مَنْ كَفَرَ ۚ وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ مَا اقْتَتَلُوا وَلَٰكِنَّ اللَّهَ يَفْعَلُ مَا يُرِيدُ
Awon Ojise wonyen, A soore ajulo fun apa kan won lori apa kan. O n be ninu won, eni ti Allahu ba soro (taara). O si se agbega awon ipo fun apa kan won. A fun (Anabi) ‘Isa omo Moryam ni awon eri t’o yanju. A tun fi Emi Mimo (iyen, molaika Jibril) ran an lowo. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, awon t’o wa leyin won iba ti bara won ja leyin ti awon eri to yanju ti de ba won. Sugbon won yapa enu (si esin ’Islam). O n be ninu won eni t’o gbagbo ni ododo (ti o je musulumi). O si n be ninu won eni t’o sai gbagbo (ti o di nasara). Ati pe ti Allahu ba fe, won iba ti ba’ra won ja, sugbon Allahu n se ohun ti O ba fe
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا أَنْفِقُوا مِمَّا رَزَقْنَاكُمْ مِنْ قَبْلِ أَنْ يَأْتِيَ يَوْمٌ لَا بَيْعٌ فِيهِ وَلَا خُلَّةٌ وَلَا شَفَاعَةٌ ۗ وَالْكَافِرُونَ هُمُ الظَّالِمُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e na ninu ohun ti A se ni arisiki fun yin siwaju ki ojo kan to de. Ko nii si tita-rira kan ninu re. Ko nii si ololufe kan, ko si nii si isipe kan (fun awon alaigbagbo). Awon alaigbagbo, awon si ni alabosi

Choose other languages: