Surah Al-Baqara Ayahs #256 Translated in Yoruba
تِلْكَ آيَاتُ اللَّهِ نَتْلُوهَا عَلَيْكَ بِالْحَقِّ ۚ وَإِنَّكَ لَمِنَ الْمُرْسَلِينَ
Iwonyi ni awon ayah Allahu, ti A n ke e fun o pelu ododo. Ati pe dajudaju iwo wa lara awon Ojise
تِلْكَ الرُّسُلُ فَضَّلْنَا بَعْضَهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ ۘ مِنْهُمْ مَنْ كَلَّمَ اللَّهُ ۖ وَرَفَعَ بَعْضَهُمْ دَرَجَاتٍ ۚ وَآتَيْنَا عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ الْبَيِّنَاتِ وَأَيَّدْنَاهُ بِرُوحِ الْقُدُسِ ۗ وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ مَا اقْتَتَلَ الَّذِينَ مِنْ بَعْدِهِمْ مِنْ بَعْدِ مَا جَاءَتْهُمُ الْبَيِّنَاتُ وَلَٰكِنِ اخْتَلَفُوا فَمِنْهُمْ مَنْ آمَنَ وَمِنْهُمْ مَنْ كَفَرَ ۚ وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ مَا اقْتَتَلُوا وَلَٰكِنَّ اللَّهَ يَفْعَلُ مَا يُرِيدُ
Awon Ojise wonyen, A soore ajulo fun apa kan won lori apa kan. O n be ninu won, eni ti Allahu ba soro (taara). O si se agbega awon ipo fun apa kan won. A fun (Anabi) ‘Isa omo Moryam ni awon eri t’o yanju. A tun fi Emi Mimo (iyen, molaika Jibril) ran an lowo. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, awon t’o wa leyin won iba ti bara won ja leyin ti awon eri to yanju ti de ba won. Sugbon won yapa enu (si esin ’Islam). O n be ninu won eni t’o gbagbo ni ododo (ti o je musulumi). O si n be ninu won eni t’o sai gbagbo (ti o di nasara). Ati pe ti Allahu ba fe, won iba ti ba’ra won ja, sugbon Allahu n se ohun ti O ba fe
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا أَنْفِقُوا مِمَّا رَزَقْنَاكُمْ مِنْ قَبْلِ أَنْ يَأْتِيَ يَوْمٌ لَا بَيْعٌ فِيهِ وَلَا خُلَّةٌ وَلَا شَفَاعَةٌ ۗ وَالْكَافِرُونَ هُمُ الظَّالِمُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e na ninu ohun ti A se ni arisiki fun yin siwaju ki ojo kan to de. Ko nii si tita-rira kan ninu re. Ko nii si ololufe kan, ko si nii si isipe kan (fun awon alaigbagbo). Awon alaigbagbo, awon si ni alabosi
اللَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ الْحَيُّ الْقَيُّومُ ۚ لَا تَأْخُذُهُ سِنَةٌ وَلَا نَوْمٌ ۚ لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۗ مَنْ ذَا الَّذِي يَشْفَعُ عِنْدَهُ إِلَّا بِإِذْنِهِ ۚ يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ ۖ وَلَا يُحِيطُونَ بِشَيْءٍ مِنْ عِلْمِهِ إِلَّا بِمَا شَاءَ ۚ وَسِعَ كُرْسِيُّهُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ ۖ وَلَا يَئُودُهُ حِفْظُهُمَا ۚ وَهُوَ الْعَلِيُّ الْعَظِيمُ
Allahu, ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun, Alaaye, Alamojuuto-eda. Oogbe ki i ta A. Ati pe oorun ki i kun Un. TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Ta ni eni ti o maa sipe lodo Re afi pelu iyonda Re? O mo ohun ti n be niwaju won ati ohun ti n be leyin won. Won ko si ni imo amotan nipa kini kan ninu imo Re afi ohun ti O ba fe (fi mo won). Aga Re gbaaye ju awon sanmo ati ile. Siso sanmo ati ile ko si da A lagara. Allahu ga, O tobi
لَا إِكْرَاهَ فِي الدِّينِ ۖ قَدْ تَبَيَّنَ الرُّشْدُ مِنَ الْغَيِّ ۚ فَمَنْ يَكْفُرْ بِالطَّاغُوتِ وَيُؤْمِنْ بِاللَّهِ فَقَدِ اسْتَمْسَكَ بِالْعُرْوَةِ الْوُثْقَىٰ لَا انْفِصَامَ لَهَا ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Ko si ijenipa ninu esin. Imona ti foju han kuro ninu isina. Enikeni ti o ba lodi si awon orisa, ti o si ni igbagbo ododo ninu Allahu, o kuku ti dimo okun t’o fokan bale julo, ti ko nii ja. Allahu ni Olugbo, Onimo
Choose other languages:

Albanian

Amharic

Azerbaijani

Bengali

Bosnian

Bulgarian

Burmese

Chinese

Danish

Dutch

English

Farsi

Filipino

French

Fulah

German

Gujarati

Hausa

Hindi

Indonesian

Italian

Japanese

Jawa

Kazakh

Khmer

Korean

Kurdish

Kyrgyz

Malay

Malayalam

Norwegian

Pashto

Persian

Polish

Portuguese

Punjabi

Russian

Sindhi

Sinhalese

Somali

Spanish

Swahili

Swedish

Tajik

Tamil

Tatar

Telugu

Thai

Turkish

Urdu

Uyghur

Uzbek

Vietnamese

Yoruba
