Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #259 Translated in Yoruba

اللَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ الْحَيُّ الْقَيُّومُ ۚ لَا تَأْخُذُهُ سِنَةٌ وَلَا نَوْمٌ ۚ لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۗ مَنْ ذَا الَّذِي يَشْفَعُ عِنْدَهُ إِلَّا بِإِذْنِهِ ۚ يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ ۖ وَلَا يُحِيطُونَ بِشَيْءٍ مِنْ عِلْمِهِ إِلَّا بِمَا شَاءَ ۚ وَسِعَ كُرْسِيُّهُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ ۖ وَلَا يَئُودُهُ حِفْظُهُمَا ۚ وَهُوَ الْعَلِيُّ الْعَظِيمُ
Allahu, ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun, Alaaye, Alamojuuto-eda. Oogbe ki i ta A. Ati pe oorun ki i kun Un. TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Ta ni eni ti o maa sipe lodo Re afi pelu iyonda Re? O mo ohun ti n be niwaju won ati ohun ti n be leyin won. Won ko si ni imo amotan nipa kini kan ninu imo Re afi ohun ti O ba fe (fi mo won). Aga Re gbaaye ju awon sanmo ati ile. Siso sanmo ati ile ko si da A lagara. Allahu ga, O tobi
لَا إِكْرَاهَ فِي الدِّينِ ۖ قَدْ تَبَيَّنَ الرُّشْدُ مِنَ الْغَيِّ ۚ فَمَنْ يَكْفُرْ بِالطَّاغُوتِ وَيُؤْمِنْ بِاللَّهِ فَقَدِ اسْتَمْسَكَ بِالْعُرْوَةِ الْوُثْقَىٰ لَا انْفِصَامَ لَهَا ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Ko si ijenipa ninu esin. Imona ti foju han kuro ninu isina. Enikeni ti o ba lodi si awon orisa, ti o si ni igbagbo ododo ninu Allahu, o kuku ti dimo okun t’o fokan bale julo, ti ko nii ja. Allahu ni Olugbo, Onimo
اللَّهُ وَلِيُّ الَّذِينَ آمَنُوا يُخْرِجُهُمْ مِنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ ۖ وَالَّذِينَ كَفَرُوا أَوْلِيَاؤُهُمُ الطَّاغُوتُ يُخْرِجُونَهُمْ مِنَ النُّورِ إِلَى الظُّلُمَاتِ ۗ أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Allahu ni Alaranse awon t’o gbagbo ni ododo. O n mu won jade kuro ninu awon okunkun wa sinu imole. Awon t’o si sai gbagbo, awon orisa ni alafeyinti won. Awon orisa n mu won jade kuro ninu imole wa sinu awon okunkun. Awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere si ni won ninu re
أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِي حَاجَّ إِبْرَاهِيمَ فِي رَبِّهِ أَنْ آتَاهُ اللَّهُ الْمُلْكَ إِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ رَبِّيَ الَّذِي يُحْيِي وَيُمِيتُ قَالَ أَنَا أُحْيِي وَأُمِيتُ ۖ قَالَ إِبْرَاهِيمُ فَإِنَّ اللَّهَ يَأْتِي بِالشَّمْسِ مِنَ الْمَشْرِقِ فَأْتِ بِهَا مِنَ الْمَغْرِبِ فَبُهِتَ الَّذِي كَفَرَ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ
Se o o ri eni t’o ba (Anabi) ’Ibrohim jiyan nipa Oluwa re, nitori pe Allahu fun un ni ijoba? Nigba ti (Anabi) ’Ibrohim so pe: “Oluwa mi ni Eni ti n so eda di alaaye. O si n so eda di oku.” O wi pe: “Emi naa n so eda di alaaye. Mo si n so eda di oku.” (Anabi) ’Ibrohim so pe: "Dajudaju Allahu n mu oorun wa lati ibuyo. Mu un wa nigba naa lati ibuwo." Won si pa oro mo eni t’o sai gbagbo lenu. Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi
أَوْ كَالَّذِي مَرَّ عَلَىٰ قَرْيَةٍ وَهِيَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا قَالَ أَنَّىٰ يُحْيِي هَٰذِهِ اللَّهُ بَعْدَ مَوْتِهَا ۖ فَأَمَاتَهُ اللَّهُ مِائَةَ عَامٍ ثُمَّ بَعَثَهُ ۖ قَالَ كَمْ لَبِثْتَ ۖ قَالَ لَبِثْتُ يَوْمًا أَوْ بَعْضَ يَوْمٍ ۖ قَالَ بَلْ لَبِثْتَ مِائَةَ عَامٍ فَانْظُرْ إِلَىٰ طَعَامِكَ وَشَرَابِكَ لَمْ يَتَسَنَّهْ ۖ وَانْظُرْ إِلَىٰ حِمَارِكَ وَلِنَجْعَلَكَ آيَةً لِلنَّاسِ ۖ وَانْظُرْ إِلَى الْعِظَامِ كَيْفَ نُنْشِزُهَا ثُمَّ نَكْسُوهَا لَحْمًا ۚ فَلَمَّا تَبَيَّنَ لَهُ قَالَ أَعْلَمُ أَنَّ اللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Tabi bi eni ti o koja ninu ilu kan nigba ti o ti tu torule-torule re. O so pe: “Bawo ni Allahu yo se so eyi di alaaye leyin iku re!” Allahu si so o di oku fun ogorun-un odun. Leyin naa, O gbe e dide. O so pe: “Igba wo ni o ti wa nibi?” O so pe: “Mo wa nibi fun ojo kan tabi ilaji ojo.” O so pe: “Bee ko, o wa nibi fun ogorun-un odun. Wo ounje re ati omi re, ko yi pada. Tun wo ketekete re, ki A le fi o se ami kan fun awon eniyan. Si tun wo eegun naa bi A o se to won papo mora won. Leyin naa, (wo) bi A o se da eran bo o lara. Nigba ti o foju han si i kedere (bee), o so pe: “Mo mo pe dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan.”

Choose other languages: