Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #131 Translated in Yoruba

وَإِذْ يَرْفَعُ إِبْرَاهِيمُ الْقَوَاعِدَ مِنَ الْبَيْتِ وَإِسْمَاعِيلُ رَبَّنَا تَقَبَّلْ مِنَّا ۖ إِنَّكَ أَنْتَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
(E ranti) nigba ti (Anabi) ’Ibrohim ati ’Ismo‘il gbe awon ipile Ile naa duro. (Won sadua pe) "Oluwa wa, gba a lowo wa, dajudaju Iwo, Iwo ni Olugbo, Onimo
رَبَّنَا وَاجْعَلْنَا مُسْلِمَيْنِ لَكَ وَمِنْ ذُرِّيَّتِنَا أُمَّةً مُسْلِمَةً لَكَ وَأَرِنَا مَنَاسِكَنَا وَتُبْ عَلَيْنَا ۖ إِنَّكَ أَنْتَ التَّوَّابُ الرَّحِيمُ
Oluwa wa, se wa ni musulumi fun O. Ki O si se ninu aromodomo wa ni ijo musulumi fun O. Fi ilana esin wa han wa. Ki O si gba ironupiwada wa. Dajudaju Iwo, Iwo ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun
رَبَّنَا وَابْعَثْ فِيهِمْ رَسُولًا مِنْهُمْ يَتْلُو عَلَيْهِمْ آيَاتِكَ وَيُعَلِّمُهُمُ الْكِتَابَ وَالْحِكْمَةَ وَيُزَكِّيهِمْ ۚ إِنَّكَ أَنْتَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Oluwa wa, gbe dide ninu won Ojise kan laaarin won, (eni ti) o maa ke awon ayah Re fun won, ti o maa ko won ni Tira ati ogbon ijinle (sunnah), ti o si maa so won di eni mimo. Dajudaju Iwo, Iwo ni Alagbara, Ologbon
وَمَنْ يَرْغَبُ عَنْ مِلَّةِ إِبْرَاهِيمَ إِلَّا مَنْ سَفِهَ نَفْسَهُ ۚ وَلَقَدِ اصْطَفَيْنَاهُ فِي الدُّنْيَا ۖ وَإِنَّهُ فِي الْآخِرَةِ لَمِنَ الصَّالِحِينَ
Ta si ni o maa ko esin (Anabi) ’Ibrohim sile afi eni ti o ba go emi ara re. A kuku ti sa a lesa n’ile aye. Dajudaju o tun wa ninu awon eni rere ni orun
إِذْ قَالَ لَهُ رَبُّهُ أَسْلِمْ ۖ قَالَ أَسْلَمْتُ لِرَبِّ الْعَالَمِينَ
(E ranti) nigba ti Oluwa re so fun un pe: “Je musulumi.” O so pe: “Mo je musulumi fun Oluwa gbogbo eda.”

Choose other languages: