Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #134 Translated in Yoruba

وَمَنْ يَرْغَبُ عَنْ مِلَّةِ إِبْرَاهِيمَ إِلَّا مَنْ سَفِهَ نَفْسَهُ ۚ وَلَقَدِ اصْطَفَيْنَاهُ فِي الدُّنْيَا ۖ وَإِنَّهُ فِي الْآخِرَةِ لَمِنَ الصَّالِحِينَ
Ta si ni o maa ko esin (Anabi) ’Ibrohim sile afi eni ti o ba go emi ara re. A kuku ti sa a lesa n’ile aye. Dajudaju o tun wa ninu awon eni rere ni orun
إِذْ قَالَ لَهُ رَبُّهُ أَسْلِمْ ۖ قَالَ أَسْلَمْتُ لِرَبِّ الْعَالَمِينَ
(E ranti) nigba ti Oluwa re so fun un pe: “Je musulumi.” O so pe: “Mo je musulumi fun Oluwa gbogbo eda.”
وَوَصَّىٰ بِهَا إِبْرَاهِيمُ بَنِيهِ وَيَعْقُوبُ يَا بَنِيَّ إِنَّ اللَّهَ اصْطَفَىٰ لَكُمُ الدِّينَ فَلَا تَمُوتُنَّ إِلَّا وَأَنْتُمْ مُسْلِمُونَ
(Anabi) ’Ibrohim si pa a lase fun awon omo re. (Anabi) Ya‘ƙub naa se bee. (Ikini keji so pe): "Eyin omo mi, dajudaju Allahu yan esin naa fun yin. Nitori naa, e o gbodo ku ayafi ki e je musulumi
أَمْ كُنْتُمْ شُهَدَاءَ إِذْ حَضَرَ يَعْقُوبَ الْمَوْتُ إِذْ قَالَ لِبَنِيهِ مَا تَعْبُدُونَ مِنْ بَعْدِي قَالُوا نَعْبُدُ إِلَٰهَكَ وَإِلَٰهَ آبَائِكَ إِبْرَاهِيمَ وَإِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ إِلَٰهًا وَاحِدًا وَنَحْنُ لَهُ مُسْلِمُونَ
Tabi eyin je elerii nigba ti iku de ba (Anabi) Ya‘ƙub? Nigba ti o so fun awon omo re pe: “Ki ni eyin yoo maa josin fun leyin (iku) mi?” Won so pe: "Awa yo maa josin fun Olohun re ati Olohun awon baba re, (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ismo‘il ati ’Ishaƙ, Olohun Okan soso. Awa si ni musulumi (ti a juwo juse sile) fun Un
تِلْكَ أُمَّةٌ قَدْ خَلَتْ ۖ لَهَا مَا كَسَبَتْ وَلَكُمْ مَا كَسَبْتُمْ ۖ وَلَا تُسْأَلُونَ عَمَّا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Ijo kan niyen ti o ti lo. Tiwon ni ohun ti won se nise. Tiyin ni ohun ti e se nise. Won ko si nii bi yin leere nipa ohun ti won n se nise

Choose other languages: