Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #137 Translated in Yoruba

أَمْ كُنْتُمْ شُهَدَاءَ إِذْ حَضَرَ يَعْقُوبَ الْمَوْتُ إِذْ قَالَ لِبَنِيهِ مَا تَعْبُدُونَ مِنْ بَعْدِي قَالُوا نَعْبُدُ إِلَٰهَكَ وَإِلَٰهَ آبَائِكَ إِبْرَاهِيمَ وَإِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ إِلَٰهًا وَاحِدًا وَنَحْنُ لَهُ مُسْلِمُونَ
Tabi eyin je elerii nigba ti iku de ba (Anabi) Ya‘ƙub? Nigba ti o so fun awon omo re pe: “Ki ni eyin yoo maa josin fun leyin (iku) mi?” Won so pe: "Awa yo maa josin fun Olohun re ati Olohun awon baba re, (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ismo‘il ati ’Ishaƙ, Olohun Okan soso. Awa si ni musulumi (ti a juwo juse sile) fun Un
تِلْكَ أُمَّةٌ قَدْ خَلَتْ ۖ لَهَا مَا كَسَبَتْ وَلَكُمْ مَا كَسَبْتُمْ ۖ وَلَا تُسْأَلُونَ عَمَّا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Ijo kan niyen ti o ti lo. Tiwon ni ohun ti won se nise. Tiyin ni ohun ti e se nise. Won ko si nii bi yin leere nipa ohun ti won n se nise
وَقَالُوا كُونُوا هُودًا أَوْ نَصَارَىٰ تَهْتَدُوا ۗ قُلْ بَلْ مِلَّةَ إِبْرَاهِيمَ حَنِيفًا ۖ وَمَا كَانَ مِنَ الْمُشْرِكِينَ
Won wi pe: “E je yehudi tabi nasara ki e mona.” So pe: "Rara, esin (Anabi) ’Ibrohim (lesin), oluduro-deede, ko si si ninu awon osebo
قُولُوا آمَنَّا بِاللَّهِ وَمَا أُنْزِلَ إِلَيْنَا وَمَا أُنْزِلَ إِلَىٰ إِبْرَاهِيمَ وَإِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ وَالْأَسْبَاطِ وَمَا أُوتِيَ مُوسَىٰ وَعِيسَىٰ وَمَا أُوتِيَ النَّبِيُّونَ مِنْ رَبِّهِمْ لَا نُفَرِّقُ بَيْنَ أَحَدٍ مِنْهُمْ وَنَحْنُ لَهُ مُسْلِمُونَ
E so pe: “A gbagbo ninu Allahu ati ohun ti Won sokale fun wa ati ohun ti Won sokale fun (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ismo‘il, ’Ishaƙ, Ya‘ƙub ati awon aromodomo Ya‘ƙub. (A gbagbo ninu) ohun ti Won fun (awon Anabi) Musa ati ‘Isa, ati ohun ti Won fun awon Anabi (yooku) lati odo Oluwa won. A ko ya eni kan soto ninu won. Awa si ni musulumi (olujuwo-juse sile) fun Un.”
فَإِنْ آمَنُوا بِمِثْلِ مَا آمَنْتُمْ بِهِ فَقَدِ اهْتَدَوْا ۖ وَإِنْ تَوَلَّوْا فَإِنَّمَا هُمْ فِي شِقَاقٍ ۖ فَسَيَكْفِيكَهُمُ اللَّهُ ۚ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
Nitori naa, ti won ba gbagbo ninu iru ohun ti e gbagbo, won ti mona. Ti won ba si gbunri, won ti wa ninu iyapa (ododo). Allahu si maa to o (nibi aburu) won. Oun ni Olugbo, Onimo

Choose other languages: