Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #97 Translated in Yoruba

وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا أَوْ قَالَ أُوحِيَ إِلَيَّ وَلَمْ يُوحَ إِلَيْهِ شَيْءٌ وَمَنْ قَالَ سَأُنْزِلُ مِثْلَ مَا أَنْزَلَ اللَّهُ ۗ وَلَوْ تَرَىٰ إِذِ الظَّالِمُونَ فِي غَمَرَاتِ الْمَوْتِ وَالْمَلَائِكَةُ بَاسِطُو أَيْدِيهِمْ أَخْرِجُوا أَنْفُسَكُمُ ۖ الْيَوْمَ تُجْزَوْنَ عَذَابَ الْهُونِ بِمَا كُنْتُمْ تَقُولُونَ عَلَى اللَّهِ غَيْرَ الْحَقِّ وَكُنْتُمْ عَنْ آيَاتِهِ تَسْتَكْبِرُونَ
Ta l’o sabosi ju eni ti o da adapa iro mo Allahu tabi eni ti o wi pe won fi imisi ranse si mi - A o si fi kini kan ranse si i - ati eni ti o wi pe "Emi naa yoo so iru ohun ti Allahu sokale kale."? Ti o ba je pe iwo ri i nigba ti awon alabosi ba wa ninu ipokaka iku, ti awon molaika nawo won (si won pe) “E mu emi yin jade wa. Lonii ni Won yoo san yin ni esan abuku iya nitori ohun ti e maa n so nipa Allahu ni aito. E si maa n se igberaga si awon ayah Re.”
وَلَقَدْ جِئْتُمُونَا فُرَادَىٰ كَمَا خَلَقْنَاكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ وَتَرَكْتُمْ مَا خَوَّلْنَاكُمْ وَرَاءَ ظُهُورِكُمْ ۖ وَمَا نَرَىٰ مَعَكُمْ شُفَعَاءَكُمُ الَّذِينَ زَعَمْتُمْ أَنَّهُمْ فِيكُمْ شُرَكَاءُ ۚ لَقَدْ تَقَطَّعَ بَيْنَكُمْ وَضَلَّ عَنْكُمْ مَا كُنْتُمْ تَزْعُمُونَ
Dajudaju e ti wa ba wa ni ikookan gege bi A se seda yin nigba akoko. E si ti fi ohun ti A fun yin sile si eyin yin. A o ma ri awon olusipe yin pelu yin, awon ti e so lai ni eri pe dajudaju laaarin yin awon ni akegbe (fun Allahu). Dajudaju asepo aarin yin ti ja patapata. Ati pe ohun ti e n so nipa won (lai ni eri lowo lori isipe yin) ti dofo mo yin lowo
إِنَّ اللَّهَ فَالِقُ الْحَبِّ وَالنَّوَىٰ ۖ يُخْرِجُ الْحَيَّ مِنَ الْمَيِّتِ وَمُخْرِجُ الْمَيِّتِ مِنَ الْحَيِّ ۚ ذَٰلِكُمُ اللَّهُ ۖ فَأَنَّىٰ تُؤْفَكُونَ
Dajudaju Allahu l’O n mu koro eso irugbin ati koro eso dabinu hu jade. O n mu alaaye jade lati ara oku. O si n mu oku jade lati ara alaaye. Iyen ni Allahu. Nitori naa, bawo ni won se n se yin lori kuro nibi ododo
فَالِقُ الْإِصْبَاحِ وَجَعَلَ اللَّيْلَ سَكَنًا وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ حُسْبَانًا ۚ ذَٰلِكَ تَقْدِيرُ الْعَزِيزِ الْعَلِيمِ
O n mu ojumo mo. O se oru ni isinmi. (O n mu) oorun ati osupa (rin) fun isiro (ojo aye). Iyen ni eto Alagbara, Onimo
وَهُوَ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ النُّجُومَ لِتَهْتَدُوا بِهَا فِي ظُلُمَاتِ الْبَرِّ وَالْبَحْرِ ۗ قَدْ فَصَّلْنَا الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ
Oun ni Eni ti O fi awon irawo se (imole) fun yin ki e le fi riran ninu okunkun ile ati ibudo. A kuku ti salaye awon ayah fun awon eniyan t’o nimo

Choose other languages: