Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #99 Translated in Yoruba

إِنَّ اللَّهَ فَالِقُ الْحَبِّ وَالنَّوَىٰ ۖ يُخْرِجُ الْحَيَّ مِنَ الْمَيِّتِ وَمُخْرِجُ الْمَيِّتِ مِنَ الْحَيِّ ۚ ذَٰلِكُمُ اللَّهُ ۖ فَأَنَّىٰ تُؤْفَكُونَ
Dajudaju Allahu l’O n mu koro eso irugbin ati koro eso dabinu hu jade. O n mu alaaye jade lati ara oku. O si n mu oku jade lati ara alaaye. Iyen ni Allahu. Nitori naa, bawo ni won se n se yin lori kuro nibi ododo
فَالِقُ الْإِصْبَاحِ وَجَعَلَ اللَّيْلَ سَكَنًا وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ حُسْبَانًا ۚ ذَٰلِكَ تَقْدِيرُ الْعَزِيزِ الْعَلِيمِ
O n mu ojumo mo. O se oru ni isinmi. (O n mu) oorun ati osupa (rin) fun isiro (ojo aye). Iyen ni eto Alagbara, Onimo
وَهُوَ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ النُّجُومَ لِتَهْتَدُوا بِهَا فِي ظُلُمَاتِ الْبَرِّ وَالْبَحْرِ ۗ قَدْ فَصَّلْنَا الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ
Oun ni Eni ti O fi awon irawo se (imole) fun yin ki e le fi riran ninu okunkun ile ati ibudo. A kuku ti salaye awon ayah fun awon eniyan t’o nimo
وَهُوَ الَّذِي أَنْشَأَكُمْ مِنْ نَفْسٍ وَاحِدَةٍ فَمُسْتَقَرٌّ وَمُسْتَوْدَعٌ ۗ قَدْ فَصَّلْنَا الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَفْقَهُونَ
Oun ni Eni ti O seda yin lati ara emi eyo kan. Nitori naa, ibugbe (nile aye) ati ibupadasi (ni orun wa fun yin). A kuku ti salaye awon ayah fun awon eniyan t’o ni agboye
وَهُوَ الَّذِي أَنْزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَخْرَجْنَا بِهِ نَبَاتَ كُلِّ شَيْءٍ فَأَخْرَجْنَا مِنْهُ خَضِرًا نُخْرِجُ مِنْهُ حَبًّا مُتَرَاكِبًا وَمِنَ النَّخْلِ مِنْ طَلْعِهَا قِنْوَانٌ دَانِيَةٌ وَجَنَّاتٍ مِنْ أَعْنَابٍ وَالزَّيْتُونَ وَالرُّمَّانَ مُشْتَبِهًا وَغَيْرَ مُتَشَابِهٍ ۗ انْظُرُوا إِلَىٰ ثَمَرِهِ إِذَا أَثْمَرَ وَيَنْعِهِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكُمْ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ
Oun ni Eni t’O n so omi kale lati sanmo. A fi mu gbogbo nnkan ogbin jade. A tun mu eweko t’o n dan logbologbo jade lati inu re. A tun n mu siri eso jade ninu re. (A si n mu jade) lati ara igi dabinu, lati ara eso akoyo re, eso t’o sujo mora won t’o ro dede wale. (A n se) awon ogba oko eso ajara, eso zaetun ati eso rummon (ni awon eso t’o) jora ati (awon eyi ti) ko jora. E wo eso re nigba ti o ba so ati (nigba ti o ba) pon. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo onigbagbo ododo

Choose other languages: