Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #109 Translated in Yoruba

وَكَذَٰلِكَ نُصَرِّفُ الْآيَاتِ وَلِيَقُولُوا دَرَسْتَ وَلِنُبَيِّنَهُ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ
Bayen ni A se n mu awon ayah wa loniran-anran ona nitori ki won le wi pe: "O kekoo (re lodo awon eniyan ni." Dipo ki won wi pe: "Won so o kale fun o ni." ati nitori ki A le se alaye re fun awon eniyan t’o nimo)
اتَّبِعْ مَا أُوحِيَ إِلَيْكَ مِنْ رَبِّكَ ۖ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ وَأَعْرِضْ عَنِ الْمُشْرِكِينَ
Tele ohun ti won fi ran o ni imisi lati odo Oluwa re. Ko si eni ti ijosin to si afi Oun. Ki o si seri kuro ni odo awon osebo
وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ مَا أَشْرَكُوا ۗ وَمَا جَعَلْنَاكَ عَلَيْهِمْ حَفِيظًا ۖ وَمَا أَنْتَ عَلَيْهِمْ بِوَكِيلٍ
Ti o ba je pe Allahu ba fe (imona fun won), won iba ti sebo. A o si fi o se oluso lori won. Ati pe iwo ko ni alamojuuto won
وَلَا تَسُبُّوا الَّذِينَ يَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ فَيَسُبُّوا اللَّهَ عَدْوًا بِغَيْرِ عِلْمٍ ۗ كَذَٰلِكَ زَيَّنَّا لِكُلِّ أُمَّةٍ عَمَلَهُمْ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّهِمْ مَرْجِعُهُمْ فَيُنَبِّئُهُمْ بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
E ma se bu awon (orisa) ti won n pe leyin Allahu, ki awon (aborisa) ma baa bu Allahu ni ti abosi ati ainimo. Bayen ni A ti se ise ijo kookan ni oso fun won. Leyin naa, odo Oluwa won ni ibupadasi won. Nitori naa, O maa fun won ni iro ohun ti won maa n se nise
وَأَقْسَمُوا بِاللَّهِ جَهْدَ أَيْمَانِهِمْ لَئِنْ جَاءَتْهُمْ آيَةٌ لَيُؤْمِنُنَّ بِهَا ۚ قُلْ إِنَّمَا الْآيَاتُ عِنْدَ اللَّهِ ۖ وَمَا يُشْعِرُكُمْ أَنَّهَا إِذَا جَاءَتْ لَا يُؤْمِنُونَ
Won si fi Allahu bura ti ibura won si lagbara gan-an pe, dajudaju ti ami (iyanu) kan ba de ba awon, awon gbodo gba a gbo. So pe: "Odo Allahu nikan ni awon ami (iyanu) wa." Ki si ni o maa mu yin fura mo pe dajudaju nigba ti o ba de (ba won) won maa gba a gbo

Choose other languages: