Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #36 Translated in Yoruba

قُلْ أَطِيعُوا اللَّهَ وَالرَّسُولَ ۖ فَإِنْ تَوَلَّوْا فَإِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ الْكَافِرِينَ
So pe: “E tele (ti) Allahu ati Ojise. Ti e ba si peyin da, dajudaju Allahu ko nifee awon alaigbagbo
إِنَّ اللَّهَ اصْطَفَىٰ آدَمَ وَنُوحًا وَآلَ إِبْرَاهِيمَ وَآلَ عِمْرَانَ عَلَى الْعَالَمِينَ
Dajudaju Allahu sa Adam, Nuh, ara ile ’Ibrohim ati ara ile ‘Imron lesa lori awon eda (asiko tiwon)
ذُرِّيَّةً بَعْضُهَا مِنْ بَعْضٍ ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Won je aromodomo; apa kan won wa lati ara apa kan. Allahu si ni Olugbo, Onimo
إِذْ قَالَتِ امْرَأَتُ عِمْرَانَ رَبِّ إِنِّي نَذَرْتُ لَكَ مَا فِي بَطْنِي مُحَرَّرًا فَتَقَبَّلْ مِنِّي ۖ إِنَّكَ أَنْتَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
(E ranti) nigba ti aya ‘Imron so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi fi ohun ti n be ninu mi jejee fun O (pe) mo maa ya a soto (fun esin Re). Nitori naa, gba a lowo mi, dajudaju Iwo ni Olugbo, Onimo
فَلَمَّا وَضَعَتْهَا قَالَتْ رَبِّ إِنِّي وَضَعْتُهَا أُنْثَىٰ وَاللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا وَضَعَتْ وَلَيْسَ الذَّكَرُ كَالْأُنْثَىٰ ۖ وَإِنِّي سَمَّيْتُهَا مَرْيَمَ وَإِنِّي أُعِيذُهَا بِكَ وَذُرِّيَّتَهَا مِنَ الشَّيْطَانِ الرَّجِيمِ
Nigba ti o bi i, o so pe: “Oluwa mi, dajudaju mo bi i ni obinrin - Allahu si nimo julo nipa ohun ti o bi – okunrin ko si da bi obinrin. Dajudaju emi so o ni Moryam. Ati pe dajudaju mo n fi O wa aabo fun oun ati aromodomo re lodo Esu, eni eko.”

Choose other languages: