Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #39 Translated in Yoruba

إِذْ قَالَتِ امْرَأَتُ عِمْرَانَ رَبِّ إِنِّي نَذَرْتُ لَكَ مَا فِي بَطْنِي مُحَرَّرًا فَتَقَبَّلْ مِنِّي ۖ إِنَّكَ أَنْتَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
(E ranti) nigba ti aya ‘Imron so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi fi ohun ti n be ninu mi jejee fun O (pe) mo maa ya a soto (fun esin Re). Nitori naa, gba a lowo mi, dajudaju Iwo ni Olugbo, Onimo
فَلَمَّا وَضَعَتْهَا قَالَتْ رَبِّ إِنِّي وَضَعْتُهَا أُنْثَىٰ وَاللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا وَضَعَتْ وَلَيْسَ الذَّكَرُ كَالْأُنْثَىٰ ۖ وَإِنِّي سَمَّيْتُهَا مَرْيَمَ وَإِنِّي أُعِيذُهَا بِكَ وَذُرِّيَّتَهَا مِنَ الشَّيْطَانِ الرَّجِيمِ
Nigba ti o bi i, o so pe: “Oluwa mi, dajudaju mo bi i ni obinrin - Allahu si nimo julo nipa ohun ti o bi – okunrin ko si da bi obinrin. Dajudaju emi so o ni Moryam. Ati pe dajudaju mo n fi O wa aabo fun oun ati aromodomo re lodo Esu, eni eko.”
فَتَقَبَّلَهَا رَبُّهَا بِقَبُولٍ حَسَنٍ وَأَنْبَتَهَا نَبَاتًا حَسَنًا وَكَفَّلَهَا زَكَرِيَّا ۖ كُلَّمَا دَخَلَ عَلَيْهَا زَكَرِيَّا الْمِحْرَابَ وَجَدَ عِنْدَهَا رِزْقًا ۖ قَالَ يَا مَرْيَمُ أَنَّىٰ لَكِ هَٰذَا ۖ قَالَتْ هُوَ مِنْ عِنْدِ اللَّهِ ۖ إِنَّ اللَّهَ يَرْزُقُ مَنْ يَشَاءُ بِغَيْرِ حِسَابٍ
Oluwa re si gba adua naa ni gbigba daadaa. O si mu omo naa dagba ni idagba daadaa. O si fi Zakariyya se alagbato re. Igbakigba ti Zakariyya ba wole to o ninu ile ijosin, o maa ba ese (eso) lodo re. (Zakariyya a) so pe: “Moryam, bawo ni eyi se je tire?” (Moryam a) so pe: "O wa lati odo Allahu. Dajudaju Allahu n se arisiki fun eni ti O ba fe ni opolopo
هُنَالِكَ دَعَا زَكَرِيَّا رَبَّهُ ۖ قَالَ رَبِّ هَبْ لِي مِنْ لَدُنْكَ ذُرِّيَّةً طَيِّبَةً ۖ إِنَّكَ سَمِيعُ الدُّعَاءِ
Ibeyen ni Zakariyya ti pe Oluwa re. O so pe: "Oluwa mi, ta mi ni ore aromodomo daadaa lati odo Re. Dajudaju Iwo ni Olugbo adua
فَنَادَتْهُ الْمَلَائِكَةُ وَهُوَ قَائِمٌ يُصَلِّي فِي الْمِحْرَابِ أَنَّ اللَّهَ يُبَشِّرُكَ بِيَحْيَىٰ مُصَدِّقًا بِكَلِمَةٍ مِنَ اللَّهِ وَسَيِّدًا وَحَصُورًا وَنَبِيًّا مِنَ الصَّالِحِينَ
Nitori naa, awon molaika pe e nigba ti o n kirun lowo ninu ile ijosin, (won so pe): "Dajudaju Allahu n fun o ni iro idunnu nipa (bibi) Yahya. O maa fi ododo rinle nipa oro kan lati odo Allahu. (O maa je) asiwaju, ti ko si nii sunmo obinrin. (O maa je) Anabi. O si wa ninu awon eni rere

Choose other languages: