Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #171 Translated in Yoruba

وَلِيَعْلَمَ الَّذِينَ نَافَقُوا ۚ وَقِيلَ لَهُمْ تَعَالَوْا قَاتِلُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ أَوِ ادْفَعُوا ۖ قَالُوا لَوْ نَعْلَمُ قِتَالًا لَاتَّبَعْنَاكُمْ ۗ هُمْ لِلْكُفْرِ يَوْمَئِذٍ أَقْرَبُ مِنْهُمْ لِلْإِيمَانِ ۚ يَقُولُونَ بِأَفْوَاهِهِمْ مَا لَيْسَ فِي قُلُوبِهِمْ ۗ وَاللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا يَكْتُمُونَ
(O tun ri bee) nitori ki O le safi han awon t’o sobe-selu (ninu awon musulumi). (Awon onigbagbo ododo) si so fun won pe: “E maa bo, ki a lo jagun fun esin Allahu tabi e wa daabo bo emi ara yin.” Won wi pe: “Awa iba mo ogun-un ja awa iba tele yin.” Won sunmo aigbagbo ni ojo yen ju igbagbo lo. Won n fi enu won so ohun ti ko si ninu okan won. Allahu si nimo julo nipa ohun ti won n fi pamo
الَّذِينَ قَالُوا لِإِخْوَانِهِمْ وَقَعَدُوا لَوْ أَطَاعُونَا مَا قُتِلُوا ۗ قُلْ فَادْرَءُوا عَنْ أَنْفُسِكُمُ الْمَوْتَ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ
Awon t’o so nipa awon omo iya won (t’o ku s’oju ogun esin) pe – ti awon si jokoo kale sile (ni tiwon), "Ti o ba je pe won tele tiwa ni, won iba ti pa won." So pe: “E yeku danu fun emi yin ti e ba je olododo.”
وَلَا تَحْسَبَنَّ الَّذِينَ قُتِلُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ أَمْوَاتًا ۚ بَلْ أَحْيَاءٌ عِنْدَ رَبِّهِمْ يُرْزَقُونَ
E ma se lero pe oku (iya) ni awon ti won pa s’oju ogun esin Allahu, amo alaaye (eni ike) ni won. Won si n pese ije-imu fun won lodo Oluwa won
فَرِحِينَ بِمَا آتَاهُمُ اللَّهُ مِنْ فَضْلِهِ وَيَسْتَبْشِرُونَ بِالَّذِينَ لَمْ يَلْحَقُوا بِهِمْ مِنْ خَلْفِهِمْ أَلَّا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ
Won n dunnu nitori ohun ti Allahu fun won ninu oore-ajulo Re. Won si n yo fun awon ti ko ti i pade won ninu awon ti won fi sile pe: “Ko si ipaya fun won. Won ko si nii banuje.”
يَسْتَبْشِرُونَ بِنِعْمَةٍ مِنَ اللَّهِ وَفَضْلٍ وَأَنَّ اللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجْرَ الْمُؤْمِنِينَ
Won n ba won yo fun ike ati oore-ajulo (ti n duro de won) lodo Allahu. Ati pe dajudaju Allahu ko nii fi esan awon onigbagbo ododo rare

Choose other languages: