Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #173 Translated in Yoruba

وَلَا تَحْسَبَنَّ الَّذِينَ قُتِلُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ أَمْوَاتًا ۚ بَلْ أَحْيَاءٌ عِنْدَ رَبِّهِمْ يُرْزَقُونَ
E ma se lero pe oku (iya) ni awon ti won pa s’oju ogun esin Allahu, amo alaaye (eni ike) ni won. Won si n pese ije-imu fun won lodo Oluwa won
فَرِحِينَ بِمَا آتَاهُمُ اللَّهُ مِنْ فَضْلِهِ وَيَسْتَبْشِرُونَ بِالَّذِينَ لَمْ يَلْحَقُوا بِهِمْ مِنْ خَلْفِهِمْ أَلَّا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ
Won n dunnu nitori ohun ti Allahu fun won ninu oore-ajulo Re. Won si n yo fun awon ti ko ti i pade won ninu awon ti won fi sile pe: “Ko si ipaya fun won. Won ko si nii banuje.”
يَسْتَبْشِرُونَ بِنِعْمَةٍ مِنَ اللَّهِ وَفَضْلٍ وَأَنَّ اللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجْرَ الْمُؤْمِنِينَ
Won n ba won yo fun ike ati oore-ajulo (ti n duro de won) lodo Allahu. Ati pe dajudaju Allahu ko nii fi esan awon onigbagbo ododo rare
الَّذِينَ اسْتَجَابُوا لِلَّهِ وَالرَّسُولِ مِنْ بَعْدِ مَا أَصَابَهُمُ الْقَرْحُ ۚ لِلَّذِينَ أَحْسَنُوا مِنْهُمْ وَاتَّقَوْا أَجْرٌ عَظِيمٌ
(Awon ni) awon t’o jepe Allahu ati Ojise leyin igba ti won ti f’ara gbogbe. Esan nla wa fun awon t’o se rere, ti won si beru (Allahu) ninu won
الَّذِينَ قَالَ لَهُمُ النَّاسُ إِنَّ النَّاسَ قَدْ جَمَعُوا لَكُمْ فَاخْشَوْهُمْ فَزَادَهُمْ إِيمَانًا وَقَالُوا حَسْبُنَا اللَّهُ وَنِعْمَ الْوَكِيلُ
(Awon ni) awon ti awon eniyan wi fun pe: “Won ma ti kora jo de yin, nitori naa e beru won.” (Eyi) lekun igbagbo ododo won. Won si so pe: “Allahu to fun wa. O si dara ni Alamoojuto.”

Choose other languages: