Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #176 Translated in Yoruba

الَّذِينَ اسْتَجَابُوا لِلَّهِ وَالرَّسُولِ مِنْ بَعْدِ مَا أَصَابَهُمُ الْقَرْحُ ۚ لِلَّذِينَ أَحْسَنُوا مِنْهُمْ وَاتَّقَوْا أَجْرٌ عَظِيمٌ
(Awon ni) awon t’o jepe Allahu ati Ojise leyin igba ti won ti f’ara gbogbe. Esan nla wa fun awon t’o se rere, ti won si beru (Allahu) ninu won
الَّذِينَ قَالَ لَهُمُ النَّاسُ إِنَّ النَّاسَ قَدْ جَمَعُوا لَكُمْ فَاخْشَوْهُمْ فَزَادَهُمْ إِيمَانًا وَقَالُوا حَسْبُنَا اللَّهُ وَنِعْمَ الْوَكِيلُ
(Awon ni) awon ti awon eniyan wi fun pe: “Won ma ti kora jo de yin, nitori naa e beru won.” (Eyi) lekun igbagbo ododo won. Won si so pe: “Allahu to fun wa. O si dara ni Alamoojuto.”
فَانْقَلَبُوا بِنِعْمَةٍ مِنَ اللَّهِ وَفَضْلٍ لَمْ يَمْسَسْهُمْ سُوءٌ وَاتَّبَعُوا رِضْوَانَ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ ذُو فَضْلٍ عَظِيمٍ
Nitori naa, won pada dele pelu ike ati oore-ajulo lati odo Allahu. Aburu kan ko si kan won. Ati pe won (sise) to iyonu Allahu. Allahu si ni Oloore nla
إِنَّمَا ذَٰلِكُمُ الشَّيْطَانُ يُخَوِّفُ أَوْلِيَاءَهُ فَلَا تَخَافُوهُمْ وَخَافُونِ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ
Dajudaju iyen ni Esu, ti n fi awon ore re deru ba yin. Nitori naa, e ma se beru won. Ki e si beru Mi ti e ba je onigbagbo ododo
وَلَا يَحْزُنْكَ الَّذِينَ يُسَارِعُونَ فِي الْكُفْرِ ۚ إِنَّهُمْ لَنْ يَضُرُّوا اللَّهَ شَيْئًا ۗ يُرِيدُ اللَّهُ أَلَّا يَجْعَلَ لَهُمْ حَظًّا فِي الْآخِرَةِ ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ
Ma se je ki awon ti n sare ko sinu aigbagbo ko ibanuje ba o. Dajudaju won ko le ko inira kan ba Allahu. Allahu ko fe ki ipin kan ninu oore wa fun won ni orun (ni); iya nla si n be fun won

Choose other languages: