Quran Apps in many lanuages:

Surah Yunus Ayahs #45 Translated in Yoruba

وَإِنْ كَذَّبُوكَ فَقُلْ لِي عَمَلِي وَلَكُمْ عَمَلُكُمْ ۖ أَنْتُمْ بَرِيئُونَ مِمَّا أَعْمَلُ وَأَنَا بَرِيءٌ مِمَّا تَعْمَلُونَ
Ti won ba pe o ni opuro, so pe: “Temi ni ise mi. Tiyin ni ise yin. Eyin yowo yose ninu ohun ti mo n se nise. Emi naa si yowo yose ninu ohun ti e n se nise.”
وَمِنْهُمْ مَنْ يَسْتَمِعُونَ إِلَيْكَ ۚ أَفَأَنْتَ تُسْمِعُ الصُّمَّ وَلَوْ كَانُوا لَا يَعْقِلُونَ
O si wa ninu won, awon t’o n teti si o. Se iwo l’o maa mu aditi gboro ni, bi o tile je pe won ki i se laakaye
وَمِنْهُمْ مَنْ يَنْظُرُ إِلَيْكَ ۚ أَفَأَنْتَ تَهْدِي الْعُمْيَ وَلَوْ كَانُوا لَا يُبْصِرُونَ
O tun n be ninu won eni t’o n wo o. Se iwo l’o maa fi afoju mona ni, bi o tile je pe won ki i riran
إِنَّ اللَّهَ لَا يَظْلِمُ النَّاسَ شَيْئًا وَلَٰكِنَّ النَّاسَ أَنْفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
Dajudaju Allahu ko nii fi kini kan sabosi si eniyan. Sugbon eniyan n sabosi si emi ara won
وَيَوْمَ يَحْشُرُهُمْ كَأَنْ لَمْ يَلْبَثُوا إِلَّا سَاعَةً مِنَ النَّهَارِ يَتَعَارَفُونَ بَيْنَهُمْ ۚ قَدْ خَسِرَ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِلِقَاءِ اللَّهِ وَمَا كَانُوا مُهْتَدِينَ
Ati pe (ranti) Ojo ti (Allahu) yoo ko won jo afi bi eni pe won ko gbe ile aye ju akoko kan ninu osan. Won yo si dara won mo. Dajudaju awon t’o pe ipade Allahu niro ti sofo; won ko si je olumona

Choose other languages: