Quran Apps in many lanuages:

Surah Yunus Ayahs #44 Translated in Yoruba

وَمِنْهُمْ مَنْ يُؤْمِنُ بِهِ وَمِنْهُمْ مَنْ لَا يُؤْمِنُ بِهِ ۚ وَرَبُّكَ أَعْلَمُ بِالْمُفْسِدِينَ
O si n be ninu won eni t’o gba a gbo ni ododo. O tun n be ninu won eni ti ko gba a gbo. Oluwa re si ni Onimo-julo nipa awon obileje
وَإِنْ كَذَّبُوكَ فَقُلْ لِي عَمَلِي وَلَكُمْ عَمَلُكُمْ ۖ أَنْتُمْ بَرِيئُونَ مِمَّا أَعْمَلُ وَأَنَا بَرِيءٌ مِمَّا تَعْمَلُونَ
Ti won ba pe o ni opuro, so pe: “Temi ni ise mi. Tiyin ni ise yin. Eyin yowo yose ninu ohun ti mo n se nise. Emi naa si yowo yose ninu ohun ti e n se nise.”
وَمِنْهُمْ مَنْ يَسْتَمِعُونَ إِلَيْكَ ۚ أَفَأَنْتَ تُسْمِعُ الصُّمَّ وَلَوْ كَانُوا لَا يَعْقِلُونَ
O si wa ninu won, awon t’o n teti si o. Se iwo l’o maa mu aditi gboro ni, bi o tile je pe won ki i se laakaye
وَمِنْهُمْ مَنْ يَنْظُرُ إِلَيْكَ ۚ أَفَأَنْتَ تَهْدِي الْعُمْيَ وَلَوْ كَانُوا لَا يُبْصِرُونَ
O tun n be ninu won eni t’o n wo o. Se iwo l’o maa fi afoju mona ni, bi o tile je pe won ki i riran
إِنَّ اللَّهَ لَا يَظْلِمُ النَّاسَ شَيْئًا وَلَٰكِنَّ النَّاسَ أَنْفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
Dajudaju Allahu ko nii fi kini kan sabosi si eniyan. Sugbon eniyan n sabosi si emi ara won

Choose other languages: