Quran Apps in many lanuages:

Surah Yunus Ayahs #108 Translated in Yoruba

قُلْ يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنْ كُنْتُمْ فِي شَكٍّ مِنْ دِينِي فَلَا أَعْبُدُ الَّذِينَ تَعْبُدُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ وَلَٰكِنْ أَعْبُدُ اللَّهَ الَّذِي يَتَوَفَّاكُمْ ۖ وَأُمِرْتُ أَنْ أَكُونَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ
So pe: “Eyin eniyan, ti e ba wa ninu iyemeji nipa esin mi. Nigba naa, emi ko nii josin fun awon ti e n josin fun leyin Allahu. Sugbon emi yoo maa josin fun Allahu, Eni ti O maa gba emi yin. Won si pa mi ni ase pe ki ng wa ninu awon onigbagbo ododo
وَأَنْ أَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفًا وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ الْمُشْرِكِينَ
(Won tun pa mi lase pe): “Doju re ko esin naa, (ki o je) oluduro-deede-ninu-esin. Iwo ko si gbodo wa ninu awon osebo
وَلَا تَدْعُ مِنْ دُونِ اللَّهِ مَا لَا يَنْفَعُكَ وَلَا يَضُرُّكَ ۖ فَإِنْ فَعَلْتَ فَإِنَّكَ إِذًا مِنَ الظَّالِمِينَ
Ati pe ma se pe leyin Allahu nnkan ti ko le se o ni anfaani, ti ko si le ko inira ba o. Ti o ba se bee nigba naa, dajudaju iwo ti wa ninu awon alabosi.”
وَإِنْ يَمْسَسْكَ اللَّهُ بِضُرٍّ فَلَا كَاشِفَ لَهُ إِلَّا هُوَ ۖ وَإِنْ يُرِدْكَ بِخَيْرٍ فَلَا رَادَّ لِفَضْلِهِ ۚ يُصِيبُ بِهِ مَنْ يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ ۚ وَهُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ
Ti Allahu ba mu inira ba o, ko si eni ti o le mu un kuro afi Oun. Ti O ba si gbero oore kan pelu re, ko si eni ti o le da oore Re pada. O n soore fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re. Oun ni Alaforijin, Asake-orun
قُلْ يَا أَيُّهَا النَّاسُ قَدْ جَاءَكُمُ الْحَقُّ مِنْ رَبِّكُمْ ۖ فَمَنِ اهْتَدَىٰ فَإِنَّمَا يَهْتَدِي لِنَفْسِهِ ۖ وَمَنْ ضَلَّ فَإِنَّمَا يَضِلُّ عَلَيْهَا ۖ وَمَا أَنَا عَلَيْكُمْ بِوَكِيلٍ
So pe: "Eyin eniyan, dajudaju ododo ti de ba yin lati odo Oluwa yin. Nitori naa, enikeni ti o ba mona, o mona fun emi ara re. Enikeni ti o ba si sina, o sina fun emi ara re. Emi si ko ni oluso fun yin

Choose other languages: