Quran Apps in many lanuages:

Surah Yunus Ayahs #107 Translated in Yoruba

ثُمَّ نُنَجِّي رُسُلَنَا وَالَّذِينَ آمَنُوا ۚ كَذَٰلِكَ حَقًّا عَلَيْنَا نُنْجِ الْمُؤْمِنِينَ
Leyin naa, A oo gba awon Ojise Wa ati awon t’o gbagbo la. Bayen ni o se je ojuse Wa lati gba awon onigbagbo ododo la
قُلْ يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنْ كُنْتُمْ فِي شَكٍّ مِنْ دِينِي فَلَا أَعْبُدُ الَّذِينَ تَعْبُدُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ وَلَٰكِنْ أَعْبُدُ اللَّهَ الَّذِي يَتَوَفَّاكُمْ ۖ وَأُمِرْتُ أَنْ أَكُونَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ
So pe: “Eyin eniyan, ti e ba wa ninu iyemeji nipa esin mi. Nigba naa, emi ko nii josin fun awon ti e n josin fun leyin Allahu. Sugbon emi yoo maa josin fun Allahu, Eni ti O maa gba emi yin. Won si pa mi ni ase pe ki ng wa ninu awon onigbagbo ododo
وَأَنْ أَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفًا وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ الْمُشْرِكِينَ
(Won tun pa mi lase pe): “Doju re ko esin naa, (ki o je) oluduro-deede-ninu-esin. Iwo ko si gbodo wa ninu awon osebo
وَلَا تَدْعُ مِنْ دُونِ اللَّهِ مَا لَا يَنْفَعُكَ وَلَا يَضُرُّكَ ۖ فَإِنْ فَعَلْتَ فَإِنَّكَ إِذًا مِنَ الظَّالِمِينَ
Ati pe ma se pe leyin Allahu nnkan ti ko le se o ni anfaani, ti ko si le ko inira ba o. Ti o ba se bee nigba naa, dajudaju iwo ti wa ninu awon alabosi.”
وَإِنْ يَمْسَسْكَ اللَّهُ بِضُرٍّ فَلَا كَاشِفَ لَهُ إِلَّا هُوَ ۖ وَإِنْ يُرِدْكَ بِخَيْرٍ فَلَا رَادَّ لِفَضْلِهِ ۚ يُصِيبُ بِهِ مَنْ يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ ۚ وَهُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ
Ti Allahu ba mu inira ba o, ko si eni ti o le mu un kuro afi Oun. Ti O ba si gbero oore kan pelu re, ko si eni ti o le da oore Re pada. O n soore fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re. Oun ni Alaforijin, Asake-orun

Choose other languages: