Quran Apps in many lanuages:

Surah Muhammad Ayahs #20 Translated in Yoruba

وَمِنْهُمْ مَنْ يَسْتَمِعُ إِلَيْكَ حَتَّىٰ إِذَا خَرَجُوا مِنْ عِنْدِكَ قَالُوا لِلَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ مَاذَا قَالَ آنِفًا ۚ أُولَٰئِكَ الَّذِينَ طَبَعَ اللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ وَاتَّبَعُوا أَهْوَاءَهُمْ
O wa ninu won, eni ti o teti si oro re titi di igba ti won ba jade kuro ni odo re tan, won yo si wi fun awon onimo-esin pe: "Ki l’o so leee kan na?" Awon wonyen ni awon ti Allahu ti di okan won pa. Won si tele ife-inu won
وَالَّذِينَ اهْتَدَوْا زَادَهُمْ هُدًى وَآتَاهُمْ تَقْوَاهُمْ
Awon t’o si tele imona, (Allahu) salekun imona fun won. O si maa fun won ni iberu won (ninu Allahu)
فَهَلْ يَنْظُرُونَ إِلَّا السَّاعَةَ أَنْ تَأْتِيَهُمْ بَغْتَةً ۖ فَقَدْ جَاءَ أَشْرَاطُهَا ۚ فَأَنَّىٰ لَهُمْ إِذَا جَاءَتْهُمْ ذِكْرَاهُمْ
Se won n reti kini kan bi ko se Akoko naa, ti o maa de ba won ni ojiji? Awon ami re kuku ti de. Nitori naa, bawo ni iranti (yo se wulo fun) won nigba ti o ba de ba won
فَاعْلَمْ أَنَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا اللَّهُ وَاسْتَغْفِرْ لِذَنْبِكَ وَلِلْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ ۗ وَاللَّهُ يَعْلَمُ مُتَقَلَّبَكُمْ وَمَثْوَاكُمْ
Nitori naa, mo pe dajudaju ko si olohun ti ijosin to si afi Allahu. Ki o si toro aforijin fun ese re ati fun awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin. Allahu mo lilo-bibo yin ati ibusinmi yin
وَيَقُولُ الَّذِينَ آمَنُوا لَوْلَا نُزِّلَتْ سُورَةٌ ۖ فَإِذَا أُنْزِلَتْ سُورَةٌ مُحْكَمَةٌ وَذُكِرَ فِيهَا الْقِتَالُ ۙ رَأَيْتَ الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمْ مَرَضٌ يَنْظُرُونَ إِلَيْكَ نَظَرَ الْمَغْشِيِّ عَلَيْهِ مِنَ الْمَوْتِ ۖ فَأَوْلَىٰ لَهُمْ
Awon t’o gbagbo ni ododo n so pe: "Ki ni ko je ki Won so surah kan kale?" Nigba ti won ba so surah alainipon-na kale, ti won si so oro ija ogun esin ninu re, iwo yoo ri awon ti arun wa ninu okan won, ti won yoo maa wo o ni wiwo bi eni pe won ti daku lo ponrangandan. Ohun ti o si dara julo fun won

Choose other languages: