Quran Apps in many lanuages:

Surah Hud Ayahs #49 Translated in Yoruba

وَنَادَىٰ نُوحٌ رَبَّهُ فَقَالَ رَبِّ إِنَّ ابْنِي مِنْ أَهْلِي وَإِنَّ وَعْدَكَ الْحَقُّ وَأَنْتَ أَحْكَمُ الْحَاكِمِينَ
(Anabi) Nuh pe Oluwa re, o si so pe: “Oluwa mi, dajudaju omo mi wa ninu ara ile mi. Ati pe dajudaju adehun Re, ododo ni. Iwo l’O si mo ejo da julo ninu awon adajo
قَالَ يَا نُوحُ إِنَّهُ لَيْسَ مِنْ أَهْلِكَ ۖ إِنَّهُ عَمَلٌ غَيْرُ صَالِحٍ ۖ فَلَا تَسْأَلْنِ مَا لَيْسَ لَكَ بِهِ عِلْمٌ ۖ إِنِّي أَعِظُكَ أَنْ تَكُونَ مِنَ الْجَاهِلِينَ
Allahu so pe: “Nuh, dajudaju ko si ninu ara ile re (ni ti esin). Dajudaju ise ti ko dara ni. Nitori naa, o o gbodo bi Mi leere nnkan ti o o ni imo nipa re. Dajudaju Emi n kilo fun o nitori ki o ma baa di ara awon alaimokan.”
قَالَ رَبِّ إِنِّي أَعُوذُ بِكَ أَنْ أَسْأَلَكَ مَا لَيْسَ لِي بِهِ عِلْمٌ ۖ وَإِلَّا تَغْفِرْ لِي وَتَرْحَمْنِي أَكُنْ مِنَ الْخَاسِرِينَ
O so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi n sa di O nibi ki ng bi O leere nnkan ti emi ko ni imo re. Ti O o ba forijin mi, ki O si saanu mi, emi yoo wa lara awon eni ofo
قِيلَ يَا نُوحُ اهْبِطْ بِسَلَامٍ مِنَّا وَبَرَكَاتٍ عَلَيْكَ وَعَلَىٰ أُمَمٍ مِمَّنْ مَعَكَ ۚ وَأُمَمٌ سَنُمَتِّعُهُمْ ثُمَّ يَمَسُّهُمْ مِنَّا عَذَابٌ أَلِيمٌ
A so pe: "Nuh, sokale pelu alaafia lati odo Wa. Ati pe ki ibukun wa pelu re ati awon ijo ninu awon t’o n be pelu re. Awon ijo kan (tun n bo), ti A oo fun won ni igbadun (oore aye). Leyin naa, iya eleta-elero yo si fowo ba won lati odo Wa
تِلْكَ مِنْ أَنْبَاءِ الْغَيْبِ نُوحِيهَا إِلَيْكَ ۖ مَا كُنْتَ تَعْلَمُهَا أَنْتَ وَلَا قَوْمُكَ مِنْ قَبْلِ هَٰذَا ۖ فَاصْبِرْ ۖ إِنَّ الْعَاقِبَةَ لِلْمُتَّقِينَ
Iwonyi wa ninu iro ikoko ti A n fi (imisi re) ranse si o. Iwo ati ijo re ko nimo re siwaju eyi (ti A sokale fun o). Nitori naa, se suuru. Dajudaju ikangun rere wa fun awon oluberu (Allahu)

Choose other languages: