Quran Apps in many lanuages:

Surah Ghafir Ayahs #42 Translated in Yoruba

وَقَالَ الَّذِي آمَنَ يَا قَوْمِ اتَّبِعُونِ أَهْدِكُمْ سَبِيلَ الرَّشَادِ
Eni t’o gbagbo ni ododo tun so pe: "Eyin eniyan mi, e tele mi, mo maa juwe yin si oju ona imona
يَا قَوْمِ إِنَّمَا هَٰذِهِ الْحَيَاةُ الدُّنْيَا مَتَاعٌ وَإِنَّ الْآخِرَةَ هِيَ دَارُ الْقَرَارِ
Eyin eniyan mi, isemi ile aye yii je igbadun lasan. Dajudaju orun si ni ile gbere
مَنْ عَمِلَ سَيِّئَةً فَلَا يُجْزَىٰ إِلَّا مِثْلَهَا ۖ وَمَنْ عَمِلَ صَالِحًا مِنْ ذَكَرٍ أَوْ أُنْثَىٰ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَأُولَٰئِكَ يَدْخُلُونَ الْجَنَّةَ يُرْزَقُونَ فِيهَا بِغَيْرِ حِسَابٍ
Eni ti o ba se aburu kan, Won ko nii san an ni esan kan ayafi iru re. Eni ti o ba si se ise rere ni okunrin tabi ni obinrin, ti o si je onigbagbo ododo, awon wonyen ni won maa wo inu Ogba Idera. Won yoo maa pese arisiki fun won ninu re lai la isiro lo
وَيَا قَوْمِ مَا لِي أَدْعُوكُمْ إِلَى النَّجَاةِ وَتَدْعُونَنِي إِلَى النَّارِ
Eyin eniyan mi, ki lo mu yin ti mo n pe yin sibi igbala, ti eyin si n pe mi sibi Ina
تَدْعُونَنِي لِأَكْفُرَ بِاللَّهِ وَأُشْرِكَ بِهِ مَا لَيْسَ لِي بِهِ عِلْمٌ وَأَنَا أَدْعُوكُمْ إِلَى الْعَزِيزِ الْغَفَّارِ
E n pe mi pe ki ng sai gbagbo ninu Allahu, ki ng si so nnkan ti emi ko nimo nipa re di akegbe fun Un. Emi si n pe yin si odo Alagbara, Alaforijin

Choose other languages: