Quran Apps in many lanuages:

Surah Ghafir Ayahs #20 Translated in Yoruba

يَوْمَ هُمْ بَارِزُونَ ۖ لَا يَخْفَىٰ عَلَى اللَّهِ مِنْهُمْ شَيْءٌ ۚ لِمَنِ الْمُلْكُ الْيَوْمَ ۖ لِلَّهِ الْوَاحِدِ الْقَهَّارِ
Ni ojo ti won yoo yo jade (lati inu saree), kini kan ko si nii pamo nipa won fun Allahu. (Allahu yo si so pe): "Ti ta ni ijoba ni ojo oni? Ti Allahu, Okan soso, Olubori ni
الْيَوْمَ تُجْزَىٰ كُلُّ نَفْسٍ بِمَا كَسَبَتْ ۚ لَا ظُلْمَ الْيَوْمَ ۚ إِنَّ اللَّهَ سَرِيعُ الْحِسَابِ
Ni oni ni A oo san emi kookan ni esan ohun ti o se nise. Ko si si abosi kan ni oni. Dajudaju Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise
وَأَنْذِرْهُمْ يَوْمَ الْآزِفَةِ إِذِ الْقُلُوبُ لَدَى الْحَنَاجِرِ كَاظِمِينَ ۚ مَا لِلظَّالِمِينَ مِنْ حَمِيمٍ وَلَا شَفِيعٍ يُطَاعُ
Ati pe sekilo ojo ti o sunmo fun won. Nigba ti awon okan ba ga de gogongo, ti o maa kun fun ibanuje, ko nii si ore imule ati olusipe kan ti won maa tele oro re lori (oro) awon alabosi
يَعْلَمُ خَائِنَةَ الْأَعْيُنِ وَمَا تُخْفِي الصُّدُورُ
(Allahu) mo oju ijanba ati ohun ti awon okan fi pamo
وَاللَّهُ يَقْضِي بِالْحَقِّ ۖ وَالَّذِينَ يَدْعُونَ مِنْ دُونِهِ لَا يَقْضُونَ بِشَيْءٍ ۗ إِنَّ اللَّهَ هُوَ السَّمِيعُ الْبَصِيرُ
Ati pe Allahu l’O maa fi ododo dajo. Awon ti won n pe leyin Re, won ko le se idajo kan kan. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Oluriran

Choose other languages: