Quran Apps in many lanuages:

Surah Fussilat Ayahs #45 Translated in Yoruba

إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا بِالذِّكْرِ لَمَّا جَاءَهُمْ ۖ وَإِنَّهُ لَكِتَابٌ عَزِيزٌ
Dajudaju awon t’o sai gbagbo ninu Tira Iranti naa (iyen, al-Ƙur’an) nigba ti o de ba won (eni iparun ni won.) Dajudaju ohun ma ni Tira t’o lagbara
لَا يَأْتِيهِ الْبَاطِلُ مِنْ بَيْنِ يَدَيْهِ وَلَا مِنْ خَلْفِهِ ۖ تَنْزِيلٌ مِنْ حَكِيمٍ حَمِيدٍ
Ibaje ko nii kan an lati iwaju re ati lati eyin re. Imisi ti won sokale ni lati odo Ologbon, Eleyin
مَا يُقَالُ لَكَ إِلَّا مَا قَدْ قِيلَ لِلرُّسُلِ مِنْ قَبْلِكَ ۚ إِنَّ رَبَّكَ لَذُو مَغْفِرَةٍ وَذُو عِقَابٍ أَلِيمٍ
Won ko so oro kan si o bi ko se ohun ti won ti so si awon Ojise t’o siwaju re. Dajudaju Oluwa re ma ni Alaforijin, O si ni iya eleta-elero (lodo)
وَلَوْ جَعَلْنَاهُ قُرْآنًا أَعْجَمِيًّا لَقَالُوا لَوْلَا فُصِّلَتْ آيَاتُهُ ۖ أَأَعْجَمِيٌّ وَعَرَبِيٌّ ۗ قُلْ هُوَ لِلَّذِينَ آمَنُوا هُدًى وَشِفَاءٌ ۖ وَالَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ فِي آذَانِهِمْ وَقْرٌ وَهُوَ عَلَيْهِمْ عَمًى ۚ أُولَٰئِكَ يُنَادَوْنَ مِنْ مَكَانٍ بَعِيدٍ
Ti o ba je pe A se al-Ƙur’an ni nnkan kike ni ede miiran yato si ede Larubawa ni, won iba wi pe: "Ki ni ko je ki Won se alaye awon ayah re?" Bawo ni al-Ƙur’an se le je ede miiran (yato si ede Larubawa), nigba ti Anabi (Muhammad s.a.w.) je Larubawa? So pe: "O je imona ati iwosan fun awon t’o gbagbo ni ododo. Awon ti ko si gbagbo, edidi wa ninu eti won. Fojunfoju si wa ninu oju won si (ododo al-Ƙur’an). Awon wonyen ni won si n pe (sibi ododo al-Ƙur’an) lati aye t’o jinna
وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ فَاخْتُلِفَ فِيهِ ۗ وَلَوْلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِنْ رَبِّكَ لَقُضِيَ بَيْنَهُمْ ۚ وَإِنَّهُمْ لَفِي شَكٍّ مِنْهُ مُرِيبٍ
A kuku fun (Anabi) Musa ni Tira. Won si yapa enu si i. Ti ko ba je pe oro kan ti o ti siwaju ni odo Oluwa re ni, A iba se idajo laaarin won. Dajudaju won tun wa ninu iyemeji t’o gbopon nipa al-Ƙur’an

Choose other languages: