Quran Apps in many lanuages:

Surah Fussilat Ayahs #43 Translated in Yoruba

وَمِنْ آيَاتِهِ أَنَّكَ تَرَى الْأَرْضَ خَاشِعَةً فَإِذَا أَنْزَلْنَا عَلَيْهَا الْمَاءَ اهْتَزَّتْ وَرَبَتْ ۚ إِنَّ الَّذِي أَحْيَاهَا لَمُحْيِي الْمَوْتَىٰ ۚ إِنَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Ninu awon ami Re tun ni pe dajudaju iwo yoo ri ile ni asale. Nigba ti A ba si so omi kale le e lori, o maa rura wa, o si maa ga (fun hihu irugbin jade). Dajudaju Eni ti O ji i, Oun ma ni Eni ti O maa so awon oku di alaaye. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan
إِنَّ الَّذِينَ يُلْحِدُونَ فِي آيَاتِنَا لَا يَخْفَوْنَ عَلَيْنَا ۗ أَفَمَنْ يُلْقَىٰ فِي النَّارِ خَيْرٌ أَمْ مَنْ يَأْتِي آمِنًا يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۚ اعْمَلُوا مَا شِئْتُمْ ۖ إِنَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
Dajudaju awon t’o n ye awon ayah Wa (sibi omiran), won ko pamo fun Wa. Se eni ti won maa ju sinu Ina l’o loore julo ni tabi eni ti o maa wa ni olufayabale ni Ojo Ajinde? E maa se ohun ti e ba fe. Dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا بِالذِّكْرِ لَمَّا جَاءَهُمْ ۖ وَإِنَّهُ لَكِتَابٌ عَزِيزٌ
Dajudaju awon t’o sai gbagbo ninu Tira Iranti naa (iyen, al-Ƙur’an) nigba ti o de ba won (eni iparun ni won.) Dajudaju ohun ma ni Tira t’o lagbara
لَا يَأْتِيهِ الْبَاطِلُ مِنْ بَيْنِ يَدَيْهِ وَلَا مِنْ خَلْفِهِ ۖ تَنْزِيلٌ مِنْ حَكِيمٍ حَمِيدٍ
Ibaje ko nii kan an lati iwaju re ati lati eyin re. Imisi ti won sokale ni lati odo Ologbon, Eleyin
مَا يُقَالُ لَكَ إِلَّا مَا قَدْ قِيلَ لِلرُّسُلِ مِنْ قَبْلِكَ ۚ إِنَّ رَبَّكَ لَذُو مَغْفِرَةٍ وَذُو عِقَابٍ أَلِيمٍ
Won ko so oro kan si o bi ko se ohun ti won ti so si awon Ojise t’o siwaju re. Dajudaju Oluwa re ma ni Alaforijin, O si ni iya eleta-elero (lodo)

Choose other languages: